ALMUDEEF TVQuran Channel

Read Quran

سُورَةُ الزَّلۡزَلَةِ

Suratul Az-Zalzala · 8 ayahs

  1. بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ إِذَا زُلْزِلَتِ ٱلْأَرْضُ زِلْزَالَهَا ﴿١﴾

    99:1Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní ìmìtìtì rẹ̀,

  2. وَأَخْرَجَتِ ٱلْأَرْضُ أَثْقَالَهَا ﴿٢﴾

    99:2àti (nígbà) tí ilẹ̀ bá tú àwọn ẹrù tó wúwo nínú rẹ̀ jáde,

  3. وَقَالَ ٱلْإِنسَٰنُ مَا لَهَا ﴿٣﴾

    99:3ènìyàn yó sì wí pé: “Kí l’ó mú un?”

  4. يَوْمَئِذٍۢ تُحَدِّثُ أَخْبَارَهَا ﴿٤﴾

    99:4Ní ọjọ́ yẹn ni (ilẹ̀) yóò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìró rẹ̀ (tí ẹ̀dá gbé orí ilẹ̀ ṣe).

  5. بِأَنَّ رَبَّكَ أَوْحَىٰ لَهَا ﴿٥﴾

    99:5Nítorí pé dájúdájú Olúwa rẹ l’Ó fún un ní àṣẹ (láti sọ̀rọ̀).

  6. يَوْمَئِذٍۢ يَصْدُرُ ٱلنَّاسُ أَشْتَاتًۭا لِّيُرَوْا۟ أَعْمَٰلَهُمْ ﴿٦﴾

    99:6Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò máa gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ nítorí kí wọ́n lè fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn wọ́n.

  7. فَمَن يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍ خَيْرًۭا يَرَهُۥ ﴿٧﴾

    99:7Nítorí náà, ẹni tí ó bá ṣe iṣẹ́ rere ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.

  8. وَمَن يَعْمَلْ مِثْقَالَ ذَرَّةٍۢ شَرًّۭا يَرَهُۥ ﴿٨﴾

    99:8Ẹni tí ó bá sì ṣe iṣẹ́ aburú ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún, ó máa rí i.

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni