Read Quran
سُورَةُ الضُّحَىٰ
Suratul Ad-Dhuhaa · 11 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلضُّحَىٰ ﴿١﴾
93:1Allāhu fi ìyálẹ̀ta búra.
وَٱلَّيْلِ إِذَا سَجَىٰ ﴿٢﴾
93:2Ó tún fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.
مَا وَدَّعَكَ رَبُّكَ وَمَا قَلَىٰ ﴿٣﴾
93:3Olúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ.
وَلَلْءَاخِرَةُ خَيْرٌۭ لَّكَ مِنَ ٱلْأُولَىٰ ﴿٤﴾
93:4Dájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé.
وَلَسَوْفَ يُعْطِيكَ رَبُّكَ فَتَرْضَىٰٓ ﴿٥﴾
93:5Dájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i.
أَلَمْ يَجِدْكَ يَتِيمًۭا فَـَٔاوَىٰ ﴿٦﴾
93:6Ṣé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé.
وَوَجَدَكَ ضَآلًّۭا فَهَدَىٰ ﴿٧﴾
93:7Ó sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́.
وَوَجَدَكَ عَآئِلًۭا فَأَغْنَىٰ ﴿٨﴾
93:8Ó tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀.
فَأَمَّا ٱلْيَتِيمَ فَلَا تَقْهَرْ ﴿٩﴾
93:9Nítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí).
وَأَمَّا ٱلسَّآئِلَ فَلَا تَنْهَرْ ﴿١٠﴾
93:10Ní ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn).
وَأَمَّا بِنِعْمَةِ رَبِّكَ فَحَدِّثْ ﴿١١﴾
93:11Ní ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde.
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni