Read Quran
سُورَةُ قُرَيۡشٍ
Suratul Quraish · 4 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ لِإِيلَٰفِ قُرَيْشٍ ﴿١﴾
106:1(Ìkẹ́ ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu) fún ìdílé Ƙuraeṣ láti wà papọ̀ nínú ààbò.
إِۦلَٰفِهِمْ رِحْلَةَ ٱلشِّتَآءِ وَٱلصَّيْفِ ﴿٢﴾
106:2(Ìkẹ́ ni sẹ́ láti ọ̀dọ̀ Allāhu) fún wọn láti wà papọ̀ nínú ààbò lórí ìrìn-àjò ní ìgbà òtútù àti ní ìgbà ooru.
فَلْيَعْبُدُوا۟ رَبَّ هَٰذَا ٱلْبَيْتِ ﴿٣﴾
106:3Nítorí náà, kí wọ́n jọ́sìn fún Olúwa Ilé (Ka‘bah) yìí.
ٱلَّذِىٓ أَطْعَمَهُم مِّن جُوعٍۢ وَءَامَنَهُم مِّنْ خَوْفٍۭ ﴿٤﴾
106:4Ẹni tí Ó fún wọn ní jíjẹ (ní àsìkò) ebi. Ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ nínú ìpáyà.
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni