Read Quran
سُورَةُ المَاعُونِ
Suratul Al-Maa'un · 7 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ أَرَءَيْتَ ٱلَّذِى يُكَذِّبُ بِٱلدِّينِ ﴿١﴾
107:1Sọ fún mi nípa ẹni tó ń pe Ọjọ́ Ẹ̀san ní irọ́!
فَذَٰلِكَ ٱلَّذِى يَدُعُّ ٱلْيَتِيمَ ﴿٢﴾
107:2Ìyẹn ni ẹni tó ń lé ọmọ-òrukàn dànù.
وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلْمِسْكِينِ ﴿٣﴾
107:3Kò sì níí gbìyànjú láti bọ́ mẹ̀kúnnù.
فَوَيْلٌۭ لِّلْمُصَلِّينَ ﴿٤﴾
107:4Ègbé ni fún àwọn (mùnááfìkí) tó ń kírun;
ٱلَّذِينَ هُمْ عَن صَلَاتِهِمْ سَاهُونَ ﴿٥﴾
107:5àwọn tó ń gbàgbé láti kírun wọn ní àsìkò rẹ̀;
ٱلَّذِينَ هُمْ يُرَآءُونَ ﴿٦﴾
107:6àwọn tó ń ṣe ṣekárími;
وَيَمْنَعُونَ ٱلْمَاعُونَ ﴿٧﴾
107:7àti pé wọ́n ń hánnà ohun èlò (fún àwọn ènìyàn).
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni