ALMUDEEF TVQuran Channel

Read Quran

سُورَةُ الوَاقِعَةِ

Suratul Al-Waaqia · 96 ayahs

  1. بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ إِذَا وَقَعَتِ ٱلْوَاقِعَةُ ﴿١﴾

    56:1Nígbà tí Ìṣẹ̀lẹ̀ (Àjíǹde) bá ṣẹlẹ̀,

  2. لَيْسَ لِوَقْعَتِهَا كَاذِبَةٌ ﴿٢﴾

    56:2- kò sí irọ́ kan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀-

  3. خَافِضَةٌۭ رَّافِعَةٌ ﴿٣﴾

    56:3ó máa mú (àwọn kan) wálẹ̀ (sínú Iná), ó sì máa gbé (àwọn kan) sókè (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra).

  4. إِذَا رُجَّتِ ٱلْأَرْضُ رَجًّۭا ﴿٤﴾

    56:4Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímìtìtì,

  5. وَبُسَّتِ ٱلْجِبَالُ بَسًّۭا ﴿٥﴾

    56:5àti nígbà tí Wọ́n bá fọ́ àwọn àpáta ní fífọ́ wómúwómú,

  6. فَكَانَتْ هَبَآءًۭ مُّنۢبَثًّۭا ﴿٦﴾

    56:6- wọ́n sì máa di eruku àfẹ́dànù -

  7. وَكُنتُمْ أَزْوَٰجًۭا ثَلَٰثَةًۭ ﴿٧﴾

    56:7ẹ̀yin sì máa jẹ́ oríṣi mẹ́ta.

  8. فَأَصْحَٰبُ ٱلْمَيْمَنَةِ مَآ أَصْحَٰبُ ٱلْمَيْمَنَةِ ﴿٨﴾

    56:8Àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún?

  9. وَأَصْحَٰبُ ٱلْمَشْـَٔمَةِ مَآ أَصْحَٰبُ ٱلْمَشْـَٔمَةِ ﴿٩﴾

    56:9Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?

  10. وَٱلسَّٰبِقُونَ ٱلسَّٰبِقُونَ ﴿١٠﴾

    56:10Àwọn aṣíwájú sì ni àwọn aṣíwájú.

  11. أُو۟لَٰٓئِكَ ٱلْمُقَرَّبُونَ ﴿١١﴾

    56:11Àwọn wọ̀nyẹn ni alásùn-únmọ́ (Allāhu)

  12. فِى جَنَّٰتِ ٱلنَّعِيمِ ﴿١٢﴾

    56:12nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.

  13. ثُلَّةٌۭ مِّنَ ٱلْأَوَّلِينَ ﴿١٣﴾

    56:13Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.

  14. وَقَلِيلٌۭ مِّنَ ٱلْءَاخِرِينَ ﴿١٤﴾

    56:14Wọ́n sì kéré nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.

  15. عَلَىٰ سُرُرٍۢ مَّوْضُونَةٍۢ ﴿١٥﴾

    56:15(Wọn yóò wà) lórí ìtẹ́ tí wọ́n fi góòlù hun.

  16. مُّتَّكِـِٔينَ عَلَيْهَا مُتَقَٰبِلِينَ ﴿١٦﴾

    56:16Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú sórí rẹ̀, wọn sì máa dojú kọra wọn.

  17. يَطُوفُ عَلَيْهِمْ وِلْدَٰنٌۭ مُّخَلَّدُونَ ﴿١٧﴾

    56:17Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí kò níí darúgbó yó sì máa lọ bọ̀ láààrin wọn

  18. بِأَكْوَابٍۢ وَأَبَارِيقَ وَكَأْسٍۢ مِّن مَّعِينٍۢ ﴿١٨﴾

    56:18pẹ̀lú àwọn ife omi, ohun ìrọmi fẹ̀ǹfẹ̀ àti ife ọtí aládùn láti inú odò kan tó ń ṣàn (káà kiri ọ̀dọ̀ wọn).

  19. لَّا يُصَدَّعُونَ عَنْهَا وَلَا يُنزِفُونَ ﴿١٩﴾

    56:19Kò níí fọ́ wọn lórí; kò sì níí mú wọn húnrìrà.

  20. وَفَٰكِهَةٍۢ مِّمَّا يَتَخَيَّرُونَ ﴿٢٠﴾

    56:20Èso tí wọn yóò máa ṣẹ̀ṣà nínú rẹ̀ (tún wà fún wọn).

  21. وَلَحْمِ طَيْرٍۢ مِّمَّا يَشْتَهُونَ ﴿٢١﴾

    56:21Àti ẹran ẹyẹ, èyí tí wọ́n ń fẹ́ (yó wà fún wọn).

  22. وَحُورٌ عِينٌۭ ﴿٢٢﴾

    56:22Àwọn obìnrin ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ (tún wà fún wọn).

  23. كَأَمْثَٰلِ ٱللُّؤْلُؤِ ٱلْمَكْنُونِ ﴿٢٣﴾

    56:23Wọ́n dà bí àlúùúlù (òkúta olówó-iye-bíye) tí wọ́n fi pamọ́ sínú apó rẹ̀.

  24. جَزَآءًۢ بِمَا كَانُوا۟ يَعْمَلُونَ ﴿٢٤﴾

    56:24(Ìwọ̀nyí ni) ẹ̀san fún ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

  25. لَا يَسْمَعُونَ فِيهَا لَغْوًۭا وَلَا تَأْثِيمًا ﴿٢٥﴾

    56:25Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.

  26. إِلَّا قِيلًۭا سَلَٰمًۭا سَلَٰمًۭا ﴿٢٦﴾

    56:26Àyàfi ọ̀rọ̀ àlàáfíà, àlàáfíà.

  27. وَأَصْحَٰبُ ٱلْيَمِينِ مَآ أَصْحَٰبُ ٱلْيَمِينِ ﴿٢٧﴾

    56:27Àwọn èrò ọwọ́ ọtún, kí ni (ó máa ti dára tó fún) àwọn èrò ọwọ́ ọtún?

  28. فِى سِدْرٍۢ مَّخْضُودٍۢ ﴿٢٨﴾

    56:28(Wọn yóò wà) ní ìdí igi tí kò ní ẹ̀gún,

  29. وَطَلْحٍۢ مَّنضُودٍۢ ﴿٢٩﴾

    56:29àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ tó so jìgbìnnì,

  30. وَظِلٍّۢ مَّمْدُودٍۢ ﴿٣٠﴾

    56:30àti ibòji tó gbòòrò,

  31. وَمَآءٍۢ مَّسْكُوبٍۢ ﴿٣١﴾

    56:31àti omi tó ń ṣàn láì dáwọ́ dúró,

  32. وَفَٰكِهَةٍۢ كَثِيرَةٍۢ ﴿٣٢﴾

    56:32àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èso,

  33. لَّا مَقْطُوعَةٍۢ وَلَا مَمْنُوعَةٍۢ ﴿٣٣﴾

    56:33tí kò níí já (ní ọ̀dọ̀ wọn), kò sì níí dèèwọ̀ (fún wọn).

  34. وَفُرُشٍۢ مَّرْفُوعَةٍ ﴿٣٤﴾

    56:34(Wọ́n máa wà lórí) ìtẹ́ tí wọ́n gbé sókè.

  35. إِنَّآ أَنشَأْنَٰهُنَّ إِنشَآءًۭ ﴿٣٥﴾

    56:35Dájúdájú Àwa dá (àwọn obìnrin Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní ẹ̀dá kan (tó yàtọ̀ sí tayé).

  36. فَجَعَلْنَٰهُنَّ أَبْكَارًا ﴿٣٦﴾

    56:36A sì ṣe wọ́n ní wúńdíá,

  37. عُرُبًا أَتْرَابًۭا ﴿٣٧﴾

    56:37olólùfẹ́ ọkọ. Wọ́n sì dọ́gba ní ọjọ́ orí.

  38. لِّأَصْحَٰبِ ٱلْيَمِينِ ﴿٣٨﴾

    56:38(Wọ́n wà) fún àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.

  39. ثُلَّةٌۭ مِّنَ ٱلْأَوَّلِينَ ﴿٣٩﴾

    56:39Wọ́n pọ̀ nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́.

  40. وَثُلَّةٌۭ مِّنَ ٱلْءَاخِرِينَ ﴿٤٠﴾

    56:40Wọ́n tún pọ̀ nínú àwọn ẹni Ìkẹ́yìn.

  41. وَأَصْحَٰبُ ٱلشِّمَالِ مَآ أَصْحَٰبُ ٱلشِّمَالِ ﴿٤١﴾

    56:41Àwọn èrò ọwọ́ òsì, kí ni (ó máa ti burú tó fún) àwọn èrò ọwọ́ òsì?

  42. فِى سَمُومٍۢ وَحَمِيمٍۢ ﴿٤٢﴾

    56:42(Wọn yóò wà) nínú atẹ́gùn gbígbóná (iná) àti omi tó gbóná parí,

  43. وَظِلٍّۢ مِّن يَحْمُومٍۢ ﴿٤٣﴾

    56:43àti ní abẹ́ ibòji eléèéfín dúdú,

  44. لَّا بَارِدٍۢ وَلَا كَرِيمٍ ﴿٤٤﴾

    56:44kò tutù, kò sì dára.

  45. إِنَّهُمْ كَانُوا۟ قَبْلَ ذَٰلِكَ مُتْرَفِينَ ﴿٤٥﴾

    56:45Dájúdájú wọ́n ti jẹ́ onígbẹdẹmukẹ ṣíwájú ìyẹn.

  46. وَكَانُوا۟ يُصِرُّونَ عَلَى ٱلْحِنثِ ٱلْعَظِيمِ ﴿٤٦﴾

    56:46Wọ́n sì máa ń ṣoríkunkun lórí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

  47. وَكَانُوا۟ يَقُولُونَ أَئِذَا مِتْنَا وَكُنَّا تُرَابًۭا وَعِظَٰمًا أَءِنَّا لَمَبْعُوثُونَ ﴿٤٧﴾

    56:47Wọ́n sì máa ń wí pé: “Ṣé nígbà tí a bá di òkú, tí a sì di erùpẹ̀ àti egungun, ǹjẹ́ Wọn yóò tún gbé wa dìde ni?

  48. أَوَءَابَآؤُنَا ٱلْأَوَّلُونَ ﴿٤٨﴾

    56:48Ṣé àti àwọn bàbá wa, àwọn ẹni àkọ́kọ́?”

  49. قُلْ إِنَّ ٱلْأَوَّلِينَ وَٱلْءَاخِرِينَ ﴿٤٩﴾

    56:49Sọ pé: “Dájúdájú àwọn ẹni àkọ́kọ́ àti àwọn ẹni Ìkẹ́yìn,

  50. لَمَجْمُوعُونَ إِلَىٰ مِيقَٰتِ يَوْمٍۢ مَّعْلُومٍۢ ﴿٥٠﴾

    56:50dájúdájú A óò kó wọn jọ papọ̀ ní àkókò ọjọ́ kan tí A ti mọ̀.”

  51. ثُمَّ إِنَّكُمْ أَيُّهَا ٱلضَّآلُّونَ ٱلْمُكَذِّبُونَ ﴿٥١﴾

    56:51Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ̀yin olùṣìnà, olùpe-òdodo-nírọ́,

  52. لَءَاكِلُونَ مِن شَجَرٍۢ مِّن زَقُّومٍۢ ﴿٥٢﴾

    56:52dájúdájú ẹ̀yin máa jẹ nínú igi zaƙƙūm (igi iwọ).

  53. فَمَالِـُٔونَ مِنْهَا ٱلْبُطُونَ ﴿٥٣﴾

    56:53Ikùn yín sì máa kún bámúbámú fún (jíjẹ) igi náà.

  54. فَشَٰرِبُونَ عَلَيْهِ مِنَ ٱلْحَمِيمِ ﴿٥٤﴾

    56:54Ẹ̀yin yó sì máa mu omi tó gbóná parí lé e lórí.

  55. فَشَٰرِبُونَ شُرْبَ ٱلْهِيمِ ﴿٥٥﴾

    56:55Ẹ̀yin yóò máa mu ún ní ìmumi ràkúnmí tí òǹgbẹ ń gbẹ.

  56. هَٰذَا نُزُلُهُمْ يَوْمَ ٱلدِّينِ ﴿٥٦﴾

    56:56Èyí ni n̄ǹkan àlejò wọn ní Ọjọ́ ẹ̀san.

  57. نَحْنُ خَلَقْنَٰكُمْ فَلَوْلَا تُصَدِّقُونَ ﴿٥٧﴾

    56:57Àwa l’A ṣẹ̀dá yín. Kí ni kò jẹ́ kí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo!

  58. أَفَرَءَيْتُم مَّا تُمْنُونَ ﴿٥٨﴾

    56:58Ẹ sọ fún Mi nípa àtọ̀ tí ẹ̀ ń dà jáde (sínú àpòlùkẹ́),

  59. ءَأَنتُمْ تَخْلُقُونَهُۥٓ أَمْ نَحْنُ ٱلْخَٰلِقُونَ ﴿٥٩﴾

    56:59ṣé ẹ̀yin lẹ ṣẹ̀dá rẹ̀ ni tàbí Àwa l’A ṣẹ̀dá rẹ̀?

  60. نَحْنُ قَدَّرْنَا بَيْنَكُمُ ٱلْمَوْتَ وَمَا نَحْنُ بِمَسْبُوقِينَ ﴿٦٠﴾

    56:60Àwa l’A yan kádàrá (ọjọ́) ikú fún gbogbo yín. Àwa kò sì lè kágara

  61. عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ أَمْثَٰلَكُمْ وَنُنشِئَكُمْ فِى مَا لَا تَعْلَمُونَ ﴿٦١﴾

    56:61láti yí irú yín padà (láti erùpẹ̀ sí alààyè), kí á sì tun yín dá (ní ọ̀tun) sínú ohun tí ẹ kò mọ̀.

  62. وَلَقَدْ عَلِمْتُمُ ٱلنَّشْأَةَ ٱلْأُولَىٰ فَلَوْلَا تَذَكَّرُونَ ﴿٦٢﴾

    56:62Ẹ kúkú mọ ìṣẹ̀dá àkọ́kọ́ (pé láti ibi àìsí ni ẹ ti di alààyè), ẹ kò ṣe lo ìrántí?

  63. أَفَرَءَيْتُم مَّا تَحْرُثُونَ ﴿٦٣﴾

    56:63Ẹ sọ fún Mi nípa n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gbìn sínú ilẹ̀,

  64. ءَأَنتُمْ تَزْرَعُونَهُۥٓ أَمْ نَحْنُ ٱلزَّٰرِعُونَ ﴿٦٤﴾

    56:64ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń jẹ́ kí ó hù jáde tàbí Àwa l’À ń jẹ́ kí ó hù jáde?

  65. لَوْ نَشَآءُ لَجَعَلْنَٰهُ حُطَٰمًۭا فَظَلْتُمْ تَفَكَّهُونَ ﴿٦٥﴾

    56:65Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá sọ ọ́ di gbígbẹ, ẹ̀yin yó sì máa ṣèèmọ̀ (tí ẹ óò máa ká àbámọ̀).

  66. إِنَّا لَمُغْرَمُونَ ﴿٦٦﴾

    56:66(Ẹ̀yin yó sì wí pé:) “Dájúdájú àwa ti di onígbèsè.”

  67. بَلْ نَحْنُ مَحْرُومُونَ ﴿٦٧﴾

    56:67(Àwọn mìíràn yó sì wí pé:) “Rárá o! Wọ́n ṣe ìkórè oko ní èèwọ̀ fún wa ni.”

  68. أَفَرَءَيْتُمُ ٱلْمَآءَ ٱلَّذِى تَشْرَبُونَ ﴿٦٨﴾

    56:68Ẹ sọ fún mi nípa omi tí ẹ̀ ń mu,

  69. ءَأَنتُمْ أَنزَلْتُمُوهُ مِنَ ٱلْمُزْنِ أَمْ نَحْنُ ٱلْمُنزِلُونَ ﴿٦٩﴾

    56:69ṣé ẹ̀yin l’ẹ̀ ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti inú ẹ̀ṣújò ni tàbí Àwa l’À ń sọ̀ ọ́ kalẹ̀?

  70. لَوْ نَشَآءُ جَعَلْنَٰهُ أُجَاجًۭا فَلَوْلَا تَشْكُرُونَ ﴿٧٠﴾

    56:70Tí A bá fẹ́ ni, Àwa ìbá ṣe é ní omi tó móró. Ẹ ò ṣe máa dúpẹ́?

  71. أَفَرَءَيْتُمُ ٱلنَّارَ ٱلَّتِى تُورُونَ ﴿٧١﴾

    56:71Ẹ sọ fún Mi nípa iná tí ẹ̀ ń dá,

  72. ءَأَنتُمْ أَنشَأْتُمْ شَجَرَتَهَآ أَمْ نَحْنُ ٱلْمُنشِـُٔونَ ﴿٧٢﴾

    56:72ṣé ẹ̀yin l’ẹ ṣẹ̀dá igi rẹ̀ ni tàbí Àwa ni Aṣẹ̀dá?

  73. نَحْنُ جَعَلْنَٰهَا تَذْكِرَةًۭ وَمَتَٰعًۭا لِّلْمُقْوِينَ ﴿٧٣﴾

    56:73Àwa ṣe iná ayé ní ìrántí (fún Iná ọ̀run) àti n̄ǹkan èlò fún àwọn onírìn-àjò.

  74. فَسَبِّحْ بِٱسْمِ رَبِّكَ ٱلْعَظِيمِ ﴿٧٤﴾

    56:74Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.

  75. ۞ فَلَآ أُقْسِمُ بِمَوَٰقِعِ ٱلنُّجُومِ ﴿٧٥﴾

    56:75Nítorí náà, Mò ń fi àwọn àyè tí ìkọ̀ọ̀kan gbólóhùn al-Ƙur’ān wà nínú sánmọ̀ búra.

  76. وَإِنَّهُۥ لَقَسَمٌۭ لَّوْ تَعْلَمُونَ عَظِيمٌ ﴿٧٦﴾

    56:76Dájúdájú ìbúra ńlá ni, tí ẹ bá mọ̀.

  77. إِنَّهُۥ لَقُرْءَانٌۭ كَرِيمٌۭ ﴿٧٧﴾

    56:77Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni n̄ǹkan kíké alápọ̀n-ọ́nlé.

  78. فِى كِتَٰبٍۢ مَّكْنُونٍۢ ﴿٧٨﴾

    56:78Ó wà nínú Tírà kan tí wọ́n ń fi ààbò bò (ìyẹn Laohul-Mahfūṭḥ).

  79. لَّا يَمَسُّهُۥٓ إِلَّا ٱلْمُطَهَّرُونَ ﴿٧٩﴾

    56:79Kò sí ẹni tó lè fọwọ́ kàn án (ní ọ̀dọ̀ Allāhu) àfi àwọn ẹni mímọ́ (ìyẹn, àwọn mọlāika).

  80. تَنزِيلٌۭ مِّن رَّبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ ﴿٨٠﴾

    56:80Wọ́n sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

  81. أَفَبِهَٰذَا ٱلْحَدِيثِ أَنتُم مُّدْهِنُونَ ﴿٨١﴾

    56:81Nítorí náà, ṣé ọ̀rọ̀ (al-Ƙur’ān) yìí l’ẹ̀ ń pè ní irọ́?

  82. وَتَجْعَلُونَ رِزْقَكُمْ أَنَّكُمْ تُكَذِّبُونَ ﴿٨٢﴾

    56:82Ẹ sì ń sọ ìdúpẹ́ arísìkí yín di pé dájúdájú ẹ̀ ń pe òdodo ní irọ́.

  83. فَلَوْلَآ إِذَا بَلَغَتِ ٱلْحُلْقُومَ ﴿٨٣﴾

    56:83Kí ni ó máa ti rí (fún yín) nígbà tí ẹ̀mí (yín) bá dé ọ̀nà ọ̀fun,

  84. وَأَنتُمْ حِينَئِذٍۢ تَنظُرُونَ ﴿٨٤﴾

    56:84tí ẹ̀yin yó sì máa wò bọ̀ọ̀ nígbà yẹn?

  85. وَنَحْنُ أَقْرَبُ إِلَيْهِ مِنكُمْ وَلَٰكِن لَّا تُبْصِرُونَ ﴿٨٥﴾

    56:85Àwa sì súnmọ́ ọn ju ẹ̀yin lọ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ríran.

  86. فَلَوْلَآ إِن كُنتُمْ غَيْرَ مَدِينِينَ ﴿٨٦﴾

    56:86Ẹ̀yin kò ṣe jẹ́ ẹni tí A ò níí gbẹ̀san lára rẹ̀,

  87. تَرْجِعُونَهَآ إِن كُنتُمْ صَٰدِقِينَ ﴿٨٧﴾

    56:87kí ẹ sì dá (ẹ̀mí tí ó fẹ́ bọ́) padà, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.

  88. فَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلْمُقَرَّبِينَ ﴿٨٨﴾

    56:88Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn alásùn-únmọ́ (Wa),

  89. فَرَوْحٌۭ وَرَيْحَانٌۭ وَجَنَّتُ نَعِيمٍۢ ﴿٨٩﴾

    56:89ìsinmi, èsè tó dára àti Ọgbà Ìdẹ̀ra (ni tirẹ̀).

  90. وَأَمَّآ إِن كَانَ مِنْ أَصْحَٰبِ ٱلْيَمِينِ ﴿٩٠﴾

    56:90Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún,

  91. فَسَلَٰمٌۭ لَّكَ مِنْ أَصْحَٰبِ ٱلْيَمِينِ ﴿٩١﴾

    56:91àlàáfíà ni fún ọ láààrin àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.

  92. وَأَمَّآ إِن كَانَ مِنَ ٱلْمُكَذِّبِينَ ٱلضَّآلِّينَ ﴿٩٢﴾

    56:92Ní ti ẹni tí ó bá wà nínú àwọn olùpe-òdodo-nírọ́, àwọn olùṣìnà,

  93. فَنُزُلٌۭ مِّنْ حَمِيمٍۢ ﴿٩٣﴾

    56:93n̄ǹkan àlejò (wọn) ni omi tó gbóná parí

  94. وَتَصْلِيَةُ جَحِيمٍ ﴿٩٤﴾

    56:94àti wíwọ inú iná Jẹhīm.

  95. إِنَّ هَٰذَا لَهُوَ حَقُّ ٱلْيَقِينِ ﴿٩٥﴾

    56:95Dájúdájú èyí, òhun ni òdodo tó dájú.

  96. فَسَبِّحْ بِٱسْمِ رَبِّكَ ٱلْعَظِيمِ ﴿٩٦﴾

    56:96Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi.

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni