Read Quran
سُورَةُ المُدَّثِّرِ
Suratul Al-Muddaththir · 56 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ يَٰٓأَيُّهَا ٱلْمُدَّثِّرُ ﴿١﴾
74:1Ìwọ olùdaṣọbora.
قُمْ فَأَنذِرْ ﴿٢﴾
74:2Dìde kí o ṣèkìlọ̀.
وَرَبَّكَ فَكَبِّرْ ﴿٣﴾
74:3Olúwa rẹ sì ni kí o gbé títóbi fún.
وَثِيَابَكَ فَطَهِّرْ ﴿٤﴾
74:4Aṣọ rẹ ni kí o fọ̀ mọ́.
وَٱلرُّجْزَ فَٱهْجُرْ ﴿٥﴾
74:5Òrìṣà ni kí o jìnnà sí.
وَلَا تَمْنُن تَسْتَكْثِرُ ﴿٦﴾
74:6Má ṣe tọrẹ nítorí kí o lè rí púpọ̀ gbà.
وَلِرَبِّكَ فَٱصْبِرْ ﴿٧﴾
74:7Olúwa rẹ ni kí o ṣe sùúrù fún.
فَإِذَا نُقِرَ فِى ٱلنَّاقُورِ ﴿٨﴾
74:8Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún àjíǹde,
فَذَٰلِكَ يَوْمَئِذٍۢ يَوْمٌ عَسِيرٌ ﴿٩﴾
74:9ìyẹn, ní ọjọ́ yẹn, ni ọjọ́ ìnira,
عَلَى ٱلْكَٰفِرِينَ غَيْرُ يَسِيرٍۢ ﴿١٠﴾
74:10tí kò níí rọrùn fún àwọn aláìgbàgbọ́.
ذَرْنِى وَمَنْ خَلَقْتُ وَحِيدًۭا ﴿١١﴾
74:11Fi Mí dá ẹni tí Mo dá ní òun nìkan (ìyẹn nínú ikùn ìyá rẹ̀).
وَجَعَلْتُ لَهُۥ مَالًۭا مَّمْدُودًۭا ﴿١٢﴾
74:12Mo sì fún un ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ dúkìá
وَبَنِينَ شُهُودًۭا ﴿١٣﴾
74:13àti àwọn ọmọkúnrin tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀.
وَمَهَّدتُّ لَهُۥ تَمْهِيدًۭا ﴿١٤﴾
74:14Mo sì fi àyè ìrọ̀rùn gbá a dáadáa.
ثُمَّ يَطْمَعُ أَنْ أَزِيدَ ﴿١٥﴾
74:15Lẹ́yìn náà, ó tún ń jẹ̀rankàn pé kí N̄g ṣe àlékún.
كَلَّآ ۖ إِنَّهُۥ كَانَ لِءَايَٰتِنَا عَنِيدًۭا ﴿١٦﴾
74:16Rárá o! Dájúdájú ó jẹ́ alátakò sí àwọn āyah Wa.
سَأُرْهِقُهُۥ صَعُودًا ﴿١٧﴾
74:17Èmi yóò la ìyà pọ́nkèpọ́nkè bọ̀ ọ́ lọ́rùn (nínú Iná)
إِنَّهُۥ فَكَّرَ وَقَدَّرَ ﴿١٨﴾
74:18Dájúdájú ó ronú (lódì nípa al-Ƙur’ān). Ó sì pinnu (ọ̀rọ̀ kan nínú ẹ̀mí rẹ̀).
فَقُتِلَ كَيْفَ قَدَّرَ ﴿١٩﴾
74:19Wọ́n sì ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.
ثُمَّ قُتِلَ كَيْفَ قَدَّرَ ﴿٢٠﴾
74:20Lẹ́yìn náà, Wọ́n tún ṣẹ́bi lé e nípa bí ó ṣe pinnu.
ثُمَّ نَظَرَ ﴿٢١﴾
74:21Lẹ́yìn náà, ó wò sùn.
ثُمَّ عَبَسَ وَبَسَرَ ﴿٢٢﴾
74:22Lẹ́yìn náà, ó fajú ro, ó sì dijú mágbárí.
ثُمَّ أَدْبَرَ وَٱسْتَكْبَرَ ﴿٢٣﴾
74:23Lẹ́yìn náà, ó pẹ̀yìndà, ó sì ṣègbéraga.
فَقَالَ إِنْ هَٰذَآ إِلَّا سِحْرٌۭ يُؤْثَرُ ﴿٢٤﴾
74:24Ó sì wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán àtọwọ́dọ́wọ́.
إِنْ هَٰذَآ إِلَّا قَوْلُ ٱلْبَشَرِ ﴿٢٥﴾
74:25Kí ni èyí bí kò ṣe ọ̀rọ̀ abara”
سَأُصْلِيهِ سَقَرَ ﴿٢٦﴾
74:26Èmi yóò fi sínú iná Saƙọr.
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا سَقَرُ ﴿٢٧﴾
74:27Kí l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ iná Saƙọr?
لَا تُبْقِى وَلَا تَذَرُ ﴿٢٨﴾
74:28(Saƙọr) kò níí ṣẹ́ ẹ kù, kò sì níí pa á tì.
لَوَّاحَةٌۭ لِّلْبَشَرِ ﴿٢٩﴾
74:29Ó máa jó awọ ara di dúdú.
عَلَيْهَا تِسْعَةَ عَشَرَ ﴿٣٠﴾
74:30(Àwọn mọlāika) mọ́kàndínlógún ni ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.
وَمَا جَعَلْنَآ أَصْحَٰبَ ٱلنَّارِ إِلَّا مَلَٰٓئِكَةًۭ ۙ وَمَا جَعَلْنَا عِدَّتَهُمْ إِلَّا فِتْنَةًۭ لِّلَّذِينَ كَفَرُوا۟ لِيَسْتَيْقِنَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَٰبَ وَيَزْدَادَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓا۟ إِيمَٰنًۭا ۙ وَلَا يَرْتَابَ ٱلَّذِينَ أُوتُوا۟ ٱلْكِتَٰبَ وَٱلْمُؤْمِنُونَ ۙ وَلِيَقُولَ ٱلَّذِينَ فِى قُلُوبِهِم مَّرَضٌۭ وَٱلْكَٰفِرُونَ مَاذَآ أَرَادَ ٱللَّهُ بِهَٰذَا مَثَلًۭا ۚ كَذَٰلِكَ يُضِلُّ ٱللَّهُ مَن يَشَآءُ وَيَهْدِى مَن يَشَآءُ ۚ وَمَا يَعْلَمُ جُنُودَ رَبِّكَ إِلَّا هُوَ ۚ وَمَا هِىَ إِلَّا ذِكْرَىٰ لِلْبَشَرِ ﴿٣١﴾
74:31Àwa kò ṣe ẹnì kan ní ẹ̀ṣọ́ Iná àfi àwọn mọlāika. Àwa kò sì ṣe òǹkà wọn (bẹ́ẹ̀) bí kò ṣe (nítorí kí ó lè jẹ́) àdánwò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àti nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà lè ní àmọ̀dájú àti nítorí kí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo lè lékún ní ìgbàgbọ́ òdodo. (Ó rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo má baà ṣeyèméjì àti nítorí kí àwọn tí àrùn wà nínú ọkàn wọn àti àwọn aláìgbàgbọ́ lè wí pé: “Kí ni Allāhu gbà lérò pẹ̀lú àpèjúwe yìí?” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣi ẹni tí Ó bá fẹ́ lọ́nà, Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sọ́nà. Kò sì sí ẹni tí ó mọ àwọn ọmọ ogun Olúwa rẹ àfi Òun náà. (Iná Saƙọr) kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe ìrántí fún abara.
كَلَّا وَٱلْقَمَرِ ﴿٣٢﴾
74:32Ẹ gbọ́! Allāhu fi òṣùpá búra.
وَٱلَّيْلِ إِذْ أَدْبَرَ ﴿٣٣﴾
74:33Ó tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra.
وَٱلصُّبْحِ إِذَآ أَسْفَرَ ﴿٣٤﴾
74:34Ó tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́ búra.
إِنَّهَا لَإِحْدَى ٱلْكُبَرِ ﴿٣٥﴾
74:35Dájúdájú (iná Saƙọr) ni ọ̀kan nínú (àwọn àdánwò) tó tóbi.
نَذِيرًۭا لِّلْبَشَرِ ﴿٣٦﴾
74:36(Ó jẹ́) ìkìlọ̀ fún abara.
لِمَن شَآءَ مِنكُمْ أَن يَتَقَدَّمَ أَوْ يَتَأَخَّرَ ﴿٣٧﴾
74:37Fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti tẹ̀ síwájú tàbí láti fà sẹ́yìn (nínú ẹ̀ṣẹ̀).
كُلُّ نَفْسٍۭ بِمَا كَسَبَتْ رَهِينَةٌ ﴿٣٨﴾
74:38Ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ni onídùúró fún ohun tó ṣe níṣẹ́.
إِلَّآ أَصْحَٰبَ ٱلْيَمِينِ ﴿٣٩﴾
74:39Àyàfi àwọn èrò ọwọ́ ọ̀tún.
فِى جَنَّٰتٍۢ يَتَسَآءَلُونَ ﴿٤٠﴾
74:40Wọn yóò máa bira wọn léèrè ọ̀rọ̀ nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra
عَنِ ٱلْمُجْرِمِينَ ﴿٤١﴾
74:41nípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pé:
مَا سَلَكَكُمْ فِى سَقَرَ ﴿٤٢﴾
74:42“Kí ni ó mu yín wọ inú iná Saƙọr?”
قَالُوا۟ لَمْ نَكُ مِنَ ٱلْمُصَلِّينَ ﴿٤٣﴾
74:43Wọn yóò wí pé: “Àwa kò sí nínú àwọn olùkírun ni.
وَلَمْ نَكُ نُطْعِمُ ٱلْمِسْكِينَ ﴿٤٤﴾
74:44Àwa kò sì sí nínú àwọn tó ń bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.
وَكُنَّا نَخُوضُ مَعَ ٱلْخَآئِضِينَ ﴿٤٥﴾
74:45Àwa sì máa ń sọ ìsọkúsọ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ.
وَكُنَّا نُكَذِّبُ بِيَوْمِ ٱلدِّينِ ﴿٤٦﴾
74:46Àti pé àwa máa ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́
حَتَّىٰٓ أَتَىٰنَا ٱلْيَقِينُ ﴿٤٧﴾
74:47títí ikú fi dé bá wa.”
فَمَا تَنفَعُهُمْ شَفَٰعَةُ ٱلشَّٰفِعِينَ ﴿٤٨﴾
74:48Ìpẹ̀ àwọn olùṣìpẹ̀ kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní.
فَمَا لَهُمْ عَنِ ٱلتَّذْكِرَةِ مُعْرِضِينَ ﴿٤٩﴾
74:49Kí ló mú wọn ná tí wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí
كَأَنَّهُمْ حُمُرٌۭ مُّسْتَنفِرَةٌۭ ﴿٥٠﴾
74:50bí ẹni pé àwọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń sá lọ,
فَرَّتْ مِن قَسْوَرَةٍۭ ﴿٥١﴾
74:51tó sá fún kìnìhún?
بَلْ يُرِيدُ كُلُّ ٱمْرِئٍۢ مِّنْهُمْ أَن يُؤْتَىٰ صُحُفًۭا مُّنَشَّرَةًۭ ﴿٥٢﴾
74:52Rárá, ńṣe ni ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń fẹ́ kí Á fún òun náà ní Tírà tí ó máa ṣeé tẹ́ han àwọn ènìyàn (bíi ti al-Ƙur’ān).
كَلَّا ۖ بَل لَّا يَخَافُونَ ٱلْءَاخِرَةَ ﴿٥٣﴾
74:53Rárá. Wọn kò páyà ọ̀run ni.
كَلَّآ إِنَّهُۥ تَذْكِرَةٌۭ ﴿٥٤﴾
74:54Ẹ gbọ́! Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.
فَمَن شَآءَ ذَكَرَهُۥ ﴿٥٥﴾
74:55Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kó rántí rẹ̀.
وَمَا يَذْكُرُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ ۚ هُوَ أَهْلُ ٱلتَّقْوَىٰ وَأَهْلُ ٱلْمَغْفِرَةِ ﴿٥٦﴾
74:56Wọn kò sì níí rántí (al-Ƙur’ān) àfi tí Allāhu bá fẹ́. (Allāhu) Òun l’a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Òun l’ó sì ni àforíjìn.
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni