ALMUDEEF TVQuran Channel

Read Quran

سُورَةُ المُطَفِّفِينَ

Suratul Al-Mutaffifin · 36 ayahs

  1. بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَيْلٌۭ لِّلْمُطَفِّفِينَ ﴿١﴾

    83:1Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù,

  2. ٱلَّذِينَ إِذَا ٱكْتَالُوا۟ عَلَى ٱلنَّاسِ يَسْتَوْفُونَ ﴿٢﴾

    83:2àwọn (òǹtajà) tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn,wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún,

  3. وَإِذَا كَالُوهُمْ أَو وَّزَنُوهُمْ يُخْسِرُونَ ﴿٣﴾

    83:3nígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù.

  4. أَلَا يَظُنُّ أُو۟لَٰٓئِكَ أَنَّهُم مَّبْعُوثُونَ ﴿٤﴾

    83:4Ṣé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde

  5. لِيَوْمٍ عَظِيمٍۢ ﴿٥﴾

    83:5ní Ọjọ́ ńlá kan?

  6. يَوْمَ يَقُومُ ٱلنَّاسُ لِرَبِّ ٱلْعَٰلَمِينَ ﴿٦﴾

    83:6Ní ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde dúró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

  7. كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلْفُجَّارِ لَفِى سِجِّينٍۢ ﴿٧﴾

    83:7Ní ti òdodo dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni burúkú (tó ń dín òṣùwọ̀n kù) kúkú máa wà nínú Sijjīn.

  8. وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا سِجِّينٌۭ ﴿٨﴾

    83:8Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Sijjīn!

  9. كِتَٰبٌۭ مَّرْقُومٌۭ ﴿٩﴾

    83:9Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn).

  10. وَيْلٌۭ يَوْمَئِذٍۢ لِّلْمُكَذِّبِينَ ﴿١٠﴾

    83:10Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́,

  11. ٱلَّذِينَ يُكَذِّبُونَ بِيَوْمِ ٱلدِّينِ ﴿١١﴾

    83:11àwọn tó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.

  12. وَمَا يُكَذِّبُ بِهِۦٓ إِلَّا كُلُّ مُعْتَدٍ أَثِيمٍ ﴿١٢﴾

    83:12Kò sì sí ẹni tó ń pè é ní irọ́ àyàfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀.

  13. إِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِ ءَايَٰتُنَا قَالَ أَسَٰطِيرُ ٱلْأَوَّلِينَ ﴿١٣﴾

    83:13Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí).”

  14. كَلَّا ۖ بَلْ ۜ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِم مَّا كَانُوا۟ يَكْسِبُونَ ﴿١٤﴾

    83:14Rárá (al-Ƙur’ān kì í ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́) bí kò ṣe pé ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ aburú l’ó jọba lórí ọkàn wọn.

  15. كَلَّآ إِنَّهُمْ عَن رَّبِّهِمْ يَوْمَئِذٍۢ لَّمَحْجُوبُونَ ﴿١٥﴾

    83:15Rárá (kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí sẹ́), dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn.

  16. ثُمَّ إِنَّهُمْ لَصَالُوا۟ ٱلْجَحِيمِ ﴿١٦﴾

    83:16Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm.

  17. ثُمَّ يُقَالُ هَٰذَا ٱلَّذِى كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ ﴿١٧﴾

    83:17Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: “Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.”

  18. كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلْأَبْرَارِ لَفِى عِلِّيِّينَ ﴿١٨﴾

    83:18Ní ti òdodo, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn.

  19. وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا عِلِّيُّونَ ﴿١٩﴾

    83:19Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ‘illiyyūn!

  20. كِتَٰبٌۭ مَّرْقُومٌۭ ﴿٢٠﴾

    83:20Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn).

  21. يَشْهَدُهُ ٱلْمُقَرَّبُونَ ﴿٢١﴾

    83:21Àwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i.

  22. إِنَّ ٱلْأَبْرَارَ لَفِى نَعِيمٍ ﴿٢٢﴾

    83:22Dájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn.

  23. عَلَى ٱلْأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ ﴿٢٣﴾

    83:23Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.

  24. تَعْرِفُ فِى وُجُوهِهِمْ نَضْرَةَ ٱلنَّعِيمِ ﴿٢٤﴾

    83:24Ìwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn.

  25. يُسْقَوْنَ مِن رَّحِيقٍۢ مَّخْتُومٍ ﴿٢٥﴾

    83:25Wọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí.

  26. خِتَٰمُهُۥ مِسْكٌۭ ۚ وَفِى ذَٰلِكَ فَلْيَتَنَافَسِ ٱلْمُتَنَٰفِسُونَ ﴿٢٦﴾

    83:26Àlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn.

  27. وَمِزَاجُهُۥ مِن تَسْنِيمٍ ﴿٢٧﴾

    83:27Tẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà).

  28. عَيْنًۭا يَشْرَبُ بِهَا ٱلْمُقَرَّبُونَ ﴿٢٨﴾

    83:28(Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu.

  29. إِنَّ ٱلَّذِينَ أَجْرَمُوا۟ كَانُوا۟ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ يَضْحَكُونَ ﴿٢٩﴾

    83:29Dájúdájú àwọn tó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín.

  30. وَإِذَا مَرُّوا۟ بِهِمْ يَتَغَامَزُونَ ﴿٣٠﴾

    83:30Nígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn olùdẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́.

  31. وَإِذَا ٱنقَلَبُوٓا۟ إِلَىٰٓ أَهْلِهِمُ ٱنقَلَبُوا۟ فَكِهِينَ ﴿٣١﴾

    83:31Nígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí.

  32. وَإِذَا رَأَوْهُمْ قَالُوٓا۟ إِنَّ هَٰٓؤُلَآءِ لَضَآلُّونَ ﴿٣٢﴾

    83:32Àti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà.”

  33. وَمَآ أُرْسِلُوا۟ عَلَيْهِمْ حَٰفِظِينَ ﴿٣٣﴾

    83:33Àwa kò sì rán wọn ní iṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn.

  34. فَٱلْيَوْمَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ مِنَ ٱلْكُفَّارِ يَضْحَكُونَ ﴿٣٤﴾

    83:34Nítorí náà, ní òní àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín.

  35. عَلَى ٱلْأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ ﴿٣٥﴾

    83:35Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.

  36. هَلْ ثُوِّبَ ٱلْكُفَّارُ مَا كَانُوا۟ يَفْعَلُونَ ﴿٣٦﴾

    83:36Ṣebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)?

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni