ALMUDEEF TVQuran Channel

Read Quran

سُورَةُ العَلَقِ

Suratul Al-Alaq · 19 ayahs

  1. بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ ٱقْرَأْ بِٱسْمِ رَبِّكَ ٱلَّذِى خَلَقَ ﴿١﴾

    96:1Ké (al-Ƙur’ān) pẹ̀lú orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá.

  2. خَلَقَ ٱلْإِنسَٰنَ مِنْ عَلَقٍ ﴿٢﴾

    96:2Ó ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara ẹ̀jẹ̀ dídì.

  3. ٱقْرَأْ وَرَبُّكَ ٱلْأَكْرَمُ ﴿٣﴾

    96:3Ké e. Olúwa rẹ ni Alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ.

  4. ٱلَّذِى عَلَّمَ بِٱلْقَلَمِ ﴿٤﴾

    96:4Ẹni tí Ó fi ìmọ̀ nípa gègé ìkọ̀wé mọ ènìyàn.

  5. عَلَّمَ ٱلْإِنسَٰنَ مَا لَمْ يَعْلَمْ ﴿٥﴾

    96:5Ó fi ìmọ̀ tí ènìyàn kò mọ̀ mọ̀ ọ́n.

  6. كَلَّآ إِنَّ ٱلْإِنسَٰنَ لَيَطْغَىٰٓ ﴿٦﴾

    96:6Ní ti òdodo, dájúdájú ènìyàn kúkú ń tayọ ẹnu-ààlà

  7. أَن رَّءَاهُ ٱسْتَغْنَىٰٓ ﴿٧﴾

    96:7nítorí pé ó rí ara rẹ̀ ní ọlọ́rọ̀.

  8. إِنَّ إِلَىٰ رَبِّكَ ٱلرُّجْعَىٰٓ ﴿٨﴾

    96:8Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni àbọ̀ ẹ̀dá.

  9. أَرَءَيْتَ ٱلَّذِى يَنْهَىٰ ﴿٩﴾

    96:9Sọ fún mi nípa ẹni tó ń kọ̀

  10. عَبْدًا إِذَا صَلَّىٰٓ ﴿١٠﴾

    96:10fún ẹrúsìn kan nígbà tí (ẹrúsìn náà) kírun!

  11. أَرَءَيْتَ إِن كَانَ عَلَى ٱلْهُدَىٰٓ ﴿١١﴾

    96:11Sọ fún mi (nípa ẹ̀san rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó wà lórí ìmọ̀nà (’Islām)

  12. أَوْ أَمَرَ بِٱلتَّقْوَىٰٓ ﴿١٢﴾

    96:12tàbí pé ó pàṣẹ ìbẹ̀rù (Allāhu)!

  13. أَرَءَيْتَ إِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰٓ ﴿١٣﴾

    96:13Sọ fún mi (nípa ìyà rẹ̀) tí ó bá jẹ́ pé ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i?

  14. أَلَمْ يَعْلَم بِأَنَّ ٱللَّهَ يَرَىٰ ﴿١٤﴾

    96:14Ṣé kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń rí (òun ni?)

  15. كَلَّا لَئِن لَّمْ يَنتَهِ لَنَسْفَعًۢا بِٱلنَّاصِيَةِ ﴿١٥﴾

    96:15Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ọ̀tá Allāhu ṣe rò ó sí. Dájúdájú tí kò bá jáwọ́ (níbi dídí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lọ́wọ́), dájúdájú A máa fi àásó orí rẹ̀ wọ́ ọ (sínú Iná);

  16. نَاصِيَةٍۢ كَٰذِبَةٍ خَاطِئَةٍۢ ﴿١٦﴾

    96:16àásó orí òpùrọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.

  17. فَلْيَدْعُ نَادِيَهُۥ ﴿١٧﴾

    96:17Nítorí náà, kí ó pe àwọn olùbájókòó rẹ̀.

  18. سَنَدْعُ ٱلزَّبَانِيَةَ ﴿١٨﴾

    96:18Àwa máa pe àwọn mọlāika ẹ̀ṣọ́ Iná.

  19. كَلَّا لَا تُطِعْهُ وَٱسْجُدْ وَٱقْتَرِب ۩ ﴿١٩﴾

    96:19Rárá (ọ̀rọ̀ kò rí bí ó ṣe ń sọ nípa Wa). Má ṣe tẹ̀lé tirẹ̀. Forí kanlẹ̀ (kí o kírun), kí o sì súnmọ́ (Allāhu).

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni