ALMUDEEF TVQuran Channel

Read Quran

سُورَةُ النَّازِعَاتِ

Suratul An-Naazi'aat · 46 ayahs

  1. بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلنَّٰزِعَٰتِ غَرْقًۭا ﴿١﴾

    79:1Allāhu fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́ búra.

  2. وَٱلنَّٰشِطَٰتِ نَشْطًۭا ﴿٢﴾

    79:2Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo búra.

  3. وَٱلسَّٰبِحَٰتِ سَبْحًۭا ﴿٣﴾

    79:3Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń yára gágá níbi àṣẹ Rẹ̀ búra.

  4. فَٱلسَّٰبِقَٰتِ سَبْقًۭا ﴿٤﴾

    79:4Ó tún fi àwọn mọlāika tó máa ṣíwájú ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra tààrà búra.

  5. فَٱلْمُدَبِّرَٰتِ أَمْرًۭا ﴿٥﴾

    79:5Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń ṣètò nínú sánmọ̀ àti ilé ayé pẹ̀lú àṣẹ Allāhu búra.

  6. يَوْمَ تَرْجُفُ ٱلرَّاجِفَةُ ﴿٦﴾

    79:6Ní ọjọ́ tí ìmìtìtì máa mi gbogbo ayé tìtì.

  7. تَتْبَعُهَا ٱلرَّادِفَةُ ﴿٧﴾

    79:7Ohun tí ó máa tẹ̀lé e máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé e.

  8. قُلُوبٌۭ يَوْمَئِذٍۢ وَاجِفَةٌ ﴿٨﴾

    79:8Àwọn ọkàn yóò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní ọjọ́ yẹn.

  9. أَبْصَٰرُهَا خَٰشِعَةٌۭ ﴿٩﴾

    79:9Ojú wọn yó sì wálẹ̀ ní ti ìyẹpẹrẹ.

  10. يَقُولُونَ أَءِنَّا لَمَرْدُودُونَ فِى ٱلْحَافِرَةِ ﴿١٠﴾

    79:10Wọn yóò wí pé: “Ṣé Wọ́n tún máa dá wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí (bíi tayé ni)?

  11. أَءِذَا كُنَّا عِظَٰمًۭا نَّخِرَةًۭ ﴿١١﴾

    79:11Ṣé nígbà tí a ti di eegun tó kẹfun tán?”

  12. قَالُوا۟ تِلْكَ إِذًۭا كَرَّةٌ خَاسِرَةٌۭ ﴿١٢﴾

    79:12Wọ́n wí pé: “Ìdápadà òfò nìyẹn nígbà náà (fún ẹni tó pè é ní irọ́.)”

  13. فَإِنَّمَا هِىَ زَجْرَةٌۭ وَٰحِدَةٌۭ ﴿١٣﴾

    79:13Nítorí náà, igbe ẹyọ kan sì ni.

  14. فَإِذَا هُم بِٱلسَّاهِرَةِ ﴿١٤﴾

    79:14Nígbà náà ni wọn yóò bára wọn lórí ilẹ̀ gban̄sasa.

  15. هَلْ أَتَىٰكَ حَدِيثُ مُوسَىٰٓ ﴿١٥﴾

    79:15Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?

  16. إِذْ نَادَىٰهُ رَبُّهُۥ بِٱلْوَادِ ٱلْمُقَدَّسِ طُوًى ﴿١٦﴾

    79:16(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ pè é ní àfonúfojì mímọ́, Tuwā.

  17. ٱذْهَبْ إِلَىٰ فِرْعَوْنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ ﴿١٧﴾

    79:17Lọ bá Fir‘aon, dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.

  18. فَقُلْ هَل لَّكَ إِلَىٰٓ أَن تَزَكَّىٰ ﴿١٨﴾

    79:18Kí o sì sọ pé: “Ǹjẹ o máa ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ (kúrò nínú àìgbàgbọ́) bí?

  19. وَأَهْدِيَكَ إِلَىٰ رَبِّكَ فَتَخْشَىٰ ﴿١٩﴾

    79:19Kí èmi sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, kí o sì páyà (Rẹ̀).”

  20. فَأَرَىٰهُ ٱلْءَايَةَ ٱلْكُبْرَىٰ ﴿٢٠﴾

    79:20Ó sì fi àmì tó tóbi hàn án.

  21. فَكَذَّبَ وَعَصَىٰ ﴿٢١﴾

    79:21(Àmọ́) ó pè é ní òpùrọ́. Ó sì yapa (rẹ̀).

  22. ثُمَّ أَدْبَرَ يَسْعَىٰ ﴿٢٢﴾

    79:22Lẹ́yìn náà, ó kẹ̀yìn sí i. Ó sì ń ṣiṣẹ́ (takò ó).

  23. فَحَشَرَ فَنَادَىٰ ﴿٢٣﴾

    79:23Ó kó (àwọn ènìyàn) jọ, ó sì ké gbàjarì.

  24. فَقَالَ أَنَا۠ رَبُّكُمُ ٱلْأَعْلَىٰ ﴿٢٤﴾

    79:24Ó sì wí pé: “Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ.”

  25. فَأَخَذَهُ ٱللَّهُ نَكَالَ ٱلْءَاخِرَةِ وَٱلْأُولَىٰٓ ﴿٢٥﴾

    79:25Nítorí náà, Allāhu gbá a mú pẹ̀lú ìyà ìkẹ́yìn àti àkọ́kọ́ (nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ìkẹ́yìn yìí àti àkọ́kọ́).

  26. إِنَّ فِى ذَٰلِكَ لَعِبْرَةًۭ لِّمَن يَخْشَىٰٓ ﴿٢٦﴾

    79:26Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún ẹni tó ń páyà (Allāhu).

  27. ءَأَنتُمْ أَشَدُّ خَلْقًا أَمِ ٱلسَّمَآءُ ۚ بَنَىٰهَا ﴿٢٧﴾

    79:27Ṣé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ?

  28. رَفَعَ سَمْكَهَا فَسَوَّىٰهَا ﴿٢٨﴾

    79:28Allāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé tó gún régé.

  29. وَأَغْطَشَ لَيْلَهَا وَأَخْرَجَ ضُحَىٰهَا ﴿٢٩﴾

    79:29Ó ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde.

  30. وَٱلْأَرْضَ بَعْدَ ذَٰلِكَ دَحَىٰهَآ ﴿٣٠﴾

    79:30Àti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn.

  31. أَخْرَجَ مِنْهَا مَآءَهَا وَمَرْعَىٰهَا ﴿٣١﴾

    79:31Ó mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀.

  32. وَٱلْجِبَالَ أَرْسَىٰهَا ﴿٣٢﴾

    79:32Àti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin.

  33. مَتَٰعًۭا لَّكُمْ وَلِأَنْعَٰمِكُمْ ﴿٣٣﴾

    79:33Ìgbádùn ni fún yín àti fún àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.

  34. فَإِذَا جَآءَتِ ٱلطَّآمَّةُ ٱلْكُبْرَىٰ ﴿٣٤﴾

    79:34Ṣùgbọ́n nígbà tí ìparun ńlá bá dé,

  35. يَوْمَ يَتَذَكَّرُ ٱلْإِنسَٰنُ مَا سَعَىٰ ﴿٣٥﴾

    79:35ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò rántí ohun tó ṣe níṣẹ́.

  36. وَبُرِّزَتِ ٱلْجَحِيمُ لِمَن يَرَىٰ ﴿٣٦﴾

    79:36Wọ́n sì máa fi Iná hàn kedere fún (gbogbo) ẹni tó ríran.

  37. فَأَمَّا مَن طَغَىٰ ﴿٣٧﴾

    79:37Nítorí náà, ní ti ẹni tó tayọ ẹnu-ààlà,

  38. وَءَاثَرَ ٱلْحَيَوٰةَ ٱلدُّنْيَا ﴿٣٨﴾

    79:38tí ó tún gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé,

  39. فَإِنَّ ٱلْجَحِيمَ هِىَ ٱلْمَأْوَىٰ ﴿٣٩﴾

    79:39dájúdájú iná Jẹhīm, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).

  40. وَأَمَّا مَنْ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِۦ وَنَهَى ٱلنَّفْسَ عَنِ ٱلْهَوَىٰ ﴿٤٠﴾

    79:40Ní ti ẹni tí ó páyà ìdúró níwájú Olúwa rẹ̀, tí ó tún kọ ìfẹ́-inú fún ẹ̀mí (ara rẹ̀),

  41. فَإِنَّ ٱلْجَنَّةَ هِىَ ٱلْمَأْوَىٰ ﴿٤١﴾

    79:41dájúdájú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).

  42. يَسْـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلسَّاعَةِ أَيَّانَ مُرْسَىٰهَا ﴿٤٢﴾

    79:42Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé: “Ìgbà wo l’ó máa ṣẹlẹ̀?”

  43. فِيمَ أَنتَ مِن ذِكْرَىٰهَآ ﴿٤٣﴾

    79:43Níbo ni ìwọ wà sí ìmọ̀ rẹ̀ ná?

  44. إِلَىٰ رَبِّكَ مُنتَهَىٰهَآ ﴿٤٤﴾

    79:44Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà.

  45. إِنَّمَآ أَنتَ مُنذِرُ مَن يَخْشَىٰهَا ﴿٤٥﴾

    79:45Ìwọ kúkú ni olùkìlọ̀ fún ẹni tó ń páyà rẹ̀.

  46. كَأَنَّهُمْ يَوْمَ يَرَوْنَهَا لَمْ يَلْبَثُوٓا۟ إِلَّا عَشِيَّةً أَوْ ضُحَىٰهَا ﴿٤٦﴾

    79:46Ní ọjọ́ tí wọ́n máa rí i, wọn máa dà bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé tayọ ìrọ̀lẹ́ tàbí ìyálẹ̀ta (ọjọ́) kan.

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni