Read Quran
سُورَةُ المُلۡكِ
Suratul Al-Mulk · 30 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ تَبَٰرَكَ ٱلَّذِى بِيَدِهِ ٱلْمُلْكُ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَىْءٍۢ قَدِيرٌ ﴿١﴾
67:1Ìbùkún ni fún Ẹni tí gbogbo ìjọba wà ní Ọwọ́ Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
ٱلَّذِى خَلَقَ ٱلْمَوْتَ وَٱلْحَيَوٰةَ لِيَبْلُوَكُمْ أَيُّكُمْ أَحْسَنُ عَمَلًۭا ۚ وَهُوَ ٱلْعَزِيزُ ٱلْغَفُورُ ﴿٢﴾
67:2Ẹni tí Ó dá ikú àti ìṣẹ̀mí nítorí kí ó lè dan yín wò; èwo nínú yín l’ó máa ṣe iṣẹ́ rere jùlọ. Òun sì ni Alágbára, Aláforíjìn.
ٱلَّذِى خَلَقَ سَبْعَ سَمَٰوَٰتٍۢ طِبَاقًۭا ۖ مَّا تَرَىٰ فِى خَلْقِ ٱلرَّحْمَٰنِ مِن تَفَٰوُتٍۢ ۖ فَٱرْجِعِ ٱلْبَصَرَ هَلْ تَرَىٰ مِن فُطُورٍۢ ﴿٣﴾
67:3Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ méje ní ìpele ìpele. O ò lè rí àìgúnrégé kan lára ẹ̀dá Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, wò ó padà, ǹjẹ́ o rí ojú sísán kan (lára sánmọ̀)?
ثُمَّ ٱرْجِعِ ٱلْبَصَرَ كَرَّتَيْنِ يَنقَلِبْ إِلَيْكَ ٱلْبَصَرُ خَاسِئًۭا وَهُوَ حَسِيرٌۭ ﴿٤﴾
67:4Lẹ́yìn náà, wò ó padà ní ẹ̀ẹ̀ mejì, kí ojú rẹ padà sí ọ̀dọ̀ rẹ pẹ̀lú ìyẹpẹrẹ. Ó sì máa káàárẹ̀.
وَلَقَدْ زَيَّنَّا ٱلسَّمَآءَ ٱلدُّنْيَا بِمَصَٰبِيحَ وَجَعَلْنَٰهَا رُجُومًۭا لِّلشَّيَٰطِينِ ۖ وَأَعْتَدْنَا لَهُمْ عَذَابَ ٱلسَّعِيرِ ﴿٥﴾
67:5Dájúdájú A ti fi (àwọn ìràwọ̀ tó ń tànmọ́lẹ̀ bí) àtùpà ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́. A tún ṣe wọ́n ni ẹ̀ta-ìràwọ̀ tí wọ́n ń jù mọ́ àwọn èṣù. A sì pèsè ìyà Iná tó ń jó sílẹ̀ dè wọ́n.
وَلِلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِرَبِّهِمْ عَذَابُ جَهَنَّمَ ۖ وَبِئْسَ ٱلْمَصِيرُ ﴿٦﴾
67:6Ìyà iná Jahanamọ sì wà fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́. Ìkángun náà sì burú.
إِذَآ أُلْقُوا۟ فِيهَا سَمِعُوا۟ لَهَا شَهِيقًۭا وَهِىَ تَفُورُ ﴿٧﴾
67:7Nígbà tí wọ́n bá jù wọ́n sínú rẹ̀, wọn yóò máa gbọ́ kíkùn rẹ̀, tí ó sì máa ru sókè.
تَكَادُ تَمَيَّزُ مِنَ ٱلْغَيْظِ ۖ كُلَّمَآ أُلْقِىَ فِيهَا فَوْجٌۭ سَأَلَهُمْ خَزَنَتُهَآ أَلَمْ يَأْتِكُمْ نَذِيرٌۭ ﴿٨﴾
67:8Iná máa fẹ́ẹ̀ pínra rẹ̀ láti ara ìbínú. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ju ìjọ kan sínú rẹ̀, àwọn ẹ̀ṣọ́ Iná yóò máa bi wọ́n léèrè pé: “Ǹjẹ́ olùkìlọ̀ kan kò wá ba yín bí?”
قَالُوا۟ بَلَىٰ قَدْ جَآءَنَا نَذِيرٌۭ فَكَذَّبْنَا وَقُلْنَا مَا نَزَّلَ ٱللَّهُ مِن شَىْءٍ إِنْ أَنتُمْ إِلَّا فِى ضَلَٰلٍۢ كَبِيرٍۢ ﴿٩﴾
67:9Wọn yóò wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, dájúdájú olùkìlọ̀ kan ti wá bá wa, ṣùgbọ́n a pè é ní òpùrọ́. A sì wí pé Allāhu kò sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀. Kí ni ẹ̀yin bí kò ṣe pé ẹ wà nínú ìṣìnà tó tóbi.”
وَقَالُوا۟ لَوْ كُنَّا نَسْمَعُ أَوْ نَعْقِلُ مَا كُنَّا فِىٓ أَصْحَٰبِ ٱلسَّعِيرِ ﴿١٠﴾
67:10Wọ́n tún wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé a gbọ́ràn ni tàbí pé a ṣe làákàyè ni, àwa kò níí wà nínú èrò inú Iná tó ń jó.”
فَٱعْتَرَفُوا۟ بِذَنۢبِهِمْ فَسُحْقًۭا لِّأَصْحَٰبِ ٱلسَّعِيرِ ﴿١١﴾
67:11Wọ́n sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí náà, ìjìnnà sí ìkẹ́ Allāhu yó wà fún àwọn èrò inú Iná tó ń jó.
إِنَّ ٱلَّذِينَ يَخْشَوْنَ رَبَّهُم بِٱلْغَيْبِ لَهُم مَّغْفِرَةٌۭ وَأَجْرٌۭ كَبِيرٌۭ ﴿١٢﴾
67:12Dájúdájú àwọn tó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀, àforíjìn àti ẹ̀san tó tóbi ń bẹ fún wọn.
وَأَسِرُّوا۟ قَوْلَكُمْ أَوِ ٱجْهَرُوا۟ بِهِۦٓ ۖ إِنَّهُۥ عَلِيمٌۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ ﴿١٣﴾
67:13Ẹ wí ọ̀rọ̀ yín ní jẹ́ẹ́jẹ́ tàbí ẹ wí i sókè, dájúdájú Òun ni Onímọ̀ nípa ohun tó wà nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá.
أَلَا يَعْلَمُ مَنْ خَلَقَ وَهُوَ ٱللَّطِيفُ ٱلْخَبِيرُ ﴿١٤﴾
67:14Ṣé kò mọ Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ni?Òun sì ni Aláàánú, Alámọ̀tán.
هُوَ ٱلَّذِى جَعَلَ لَكُمُ ٱلْأَرْضَ ذَلُولًۭا فَٱمْشُوا۟ فِى مَنَاكِبِهَا وَكُلُوا۟ مِن رِّزْقِهِۦ ۖ وَإِلَيْهِ ٱلنُّشُورُ ﴿١٥﴾
67:15Òun ni Ẹni tí Ó rọ ilẹ̀ fún yín. Nítorí náà, ẹ rìn ní àwọn agbègbè rẹ̀ káàkiri, kí ẹ sì jẹ nínú arísìkí Rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àjíǹde ẹ̀dá wà.
ءَأَمِنتُم مَّن فِى ٱلسَّمَآءِ أَن يَخْسِفَ بِكُمُ ٱلْأَرْضَ فَإِذَا هِىَ تَمُورُ ﴿١٦﴾
67:16Ṣé ẹ fọkànbalẹ̀ sí Ẹni tí Ó wà ní (òkè) sánmọ̀ pé kò lè jẹ́ kí ilẹ̀ gbe yín mì? Nígbà náà, ilẹ̀ yó sì máa mì tìtì.
أَمْ أَمِنتُم مَّن فِى ٱلسَّمَآءِ أَن يُرْسِلَ عَلَيْكُمْ حَاصِبًۭا ۖ فَسَتَعْلَمُونَ كَيْفَ نَذِيرِ ﴿١٧﴾
67:17Tàbí ẹ̀ fọkànbalẹ̀ sí Ẹni tí Ó wà ní (òkè) sánmọ̀ pé kò lè fi òkúta iná ránṣẹ́ si yín ni? Nígbà náà, ẹ sì máa mọ bí ìkìlọ̀ Mi ti rí.
وَلَقَدْ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبْلِهِمْ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ ﴿١٨﴾
67:18Àwọn tó ṣíwájú wọn kúkú pe òdodo ní irọ́. Báwo sì ni bí Mo ṣe (fi ìyà) kọ (aburú fún wọn) ti rí!
أَوَلَمْ يَرَوْا۟ إِلَى ٱلطَّيْرِ فَوْقَهُمْ صَٰٓفَّٰتٍۢ وَيَقْبِضْنَ ۚ مَا يُمْسِكُهُنَّ إِلَّا ٱلرَّحْمَٰنُ ۚ إِنَّهُۥ بِكُلِّ شَىْءٍۭ بَصِيرٌ ﴿١٩﴾
67:19Ṣé wọn kò rí àwọn ẹyẹ tí ó wà ní òkè wọn, tí (wọ́n) ń na ìyẹ́ apá (wọn), tí wọ́n sì ń pa á mọ́ra? Kiní kan kò mú wọn dúró (sínú òfurufú) àfi Àjọkẹ́-ayé. Dájúdájú Òun sì ni Olùríran nípa gbogbo n̄ǹkan.
أَمَّنْ هَٰذَا ٱلَّذِى هُوَ جُندٌۭ لَّكُمْ يَنصُرُكُم مِّن دُونِ ٱلرَّحْمَٰنِ ۚ إِنِ ٱلْكَٰفِرُونَ إِلَّا فِى غُرُورٍ ﴿٢٠﴾
67:20Ta ni ẹni tí ó máa jẹ́ ọmọ ogun fún yín, tí ó máa ràn yín lọ́wọ́ lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé? (Nínú) kí ni àwọn aláìgbàgbọ́ wà bí kò ṣe nínú ẹ̀tàn.
أَمَّنْ هَٰذَا ٱلَّذِى يَرْزُقُكُمْ إِنْ أَمْسَكَ رِزْقَهُۥ ۚ بَل لَّجُّوا۟ فِى عُتُوٍّۢ وَنُفُورٍ ﴿٢١﴾
67:21Ta ni ẹni tí ó máa pèsè fún yín tí Ó bá dá arísìkí Rẹ̀ dúró? Ńṣe ni wọ́n ń ṣorí kunkun sí i nínú ìgbéraga àti sísá fún òdodo.
أَفَمَن يَمْشِى مُكِبًّا عَلَىٰ وَجْهِهِۦٓ أَهْدَىٰٓ أَمَّن يَمْشِى سَوِيًّا عَلَىٰ صِرَٰطٍۢ مُّسْتَقِيمٍۢ ﴿٢٢﴾
67:22Ǹjẹ́ ẹni tó ń rìn ní ìdojúbolẹ̀ l’ó mọ̀nà jùlọ ni tàbí ẹni tó ń rìn sàn án lójú ọ̀nà tààrà?
قُلْ هُوَ ٱلَّذِىٓ أَنشَأَكُمْ وَجَعَلَ لَكُمُ ٱلسَّمْعَ وَٱلْأَبْصَٰرَ وَٱلْأَفْـِٔدَةَ ۖ قَلِيلًۭا مَّا تَشْكُرُونَ ﴿٢٣﴾
67:23Sọ pé: “Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín. Ó sì ṣe ìgbọ́rọ̀, ìríran àti àwọn ọkàn fún yín. Ọpẹ́ tí ẹ̀ ń dá sì kéré púpọ̀.”
قُلْ هُوَ ٱلَّذِى ذَرَأَكُمْ فِى ٱلْأَرْضِ وَإِلَيْهِ تُحْشَرُونَ ﴿٢٤﴾
67:24Sọ pé: “Òun ni Ẹni tí Ó da yín sí orí ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò ko yín jọ sí.”
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلْوَعْدُ إِن كُنتُمْ صَٰدِقِينَ ﴿٢٥﴾
67:25Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”
قُلْ إِنَّمَا ٱلْعِلْمُ عِندَ ٱللَّهِ وَإِنَّمَآ أَنَا۠ نَذِيرٌۭ مُّبِينٌۭ ﴿٢٦﴾
67:26Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ni ìmọ̀ (nípa) rẹ̀ wà. Èmi kàn jẹ́ olùkìlọ̀ pọ́nńbélé ni.”
فَلَمَّا رَأَوْهُ زُلْفَةًۭ سِيٓـَٔتْ وُجُوهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ وَقِيلَ هَٰذَا ٱلَّذِى كُنتُم بِهِۦ تَدَّعُونَ ﴿٢٧﴾
67:27Nígbà tí wọ́n bá rí i tó súnmọ́, ojú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò korò wá fún ìbànújẹ́. A ó sì sọ fún wọn pé: “Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè.”
قُلْ أَرَءَيْتُمْ إِنْ أَهْلَكَنِىَ ٱللَّهُ وَمَن مَّعِىَ أَوْ رَحِمَنَا فَمَن يُجِيرُ ٱلْكَٰفِرِينَ مِنْ عَذَابٍ أَلِيمٍۢ ﴿٢٨﴾
67:28Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá pa èmi àti àwọn tó wà pẹ̀lú mi rẹ́, tàbí tí Ó bá kẹ́ wa (ṣé ẹ lè dí I lọ́wọ́ ni?) Nítorí náà, ta ni ó máa gba àwọn aláìgbàgbọ́ là nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro?
قُلْ هُوَ ٱلرَّحْمَٰنُ ءَامَنَّا بِهِۦ وَعَلَيْهِ تَوَكَّلْنَا ۖ فَسَتَعْلَمُونَ مَنْ هُوَ فِى ضَلَٰلٍۢ مُّبِينٍۢ ﴿٢٩﴾
67:29Sọ pé: “Òun ni Àjọkẹ́-ayé. Àwa gbà Á gbọ́. Òun sì la gbáralé. Láìpẹ́ ẹ máa mọ ta ni ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”
قُلْ أَرَءَيْتُمْ إِنْ أَصْبَحَ مَآؤُكُمْ غَوْرًۭا فَمَن يَأْتِيكُم بِمَآءٍۢ مَّعِينٍۭ ﴿٣٠﴾
67:30Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí omi yín bá gbẹ wá, ta ni ẹni tí ó máa mú omi tó ń ṣàn wá fún yín?”
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni