Read Quran
سُورَةُ الهُمَزَةِ
Suratul Al-Humaza · 9 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَيْلٌۭ لِّكُلِّ هُمَزَةٍۢ لُّمَزَةٍ ﴿١﴾
104:1Ègbé ni fún gbogbo abúnilójú-ẹni, abúnilẹ́yìn-ẹni,
ٱلَّذِى جَمَعَ مَالًۭا وَعَدَّدَهُۥ ﴿٢﴾
104:2ẹni tí ó kó dúkìá jọ, tí ó sì kà á lákàtúnkà (láì ná an fún ẹ̀sìn).
يَحْسَبُ أَنَّ مَالَهُۥٓ أَخْلَدَهُۥ ﴿٣﴾
104:3Ó ń lérò pé dájúdájú dúkìá rẹ̀ yóò mú un ṣe gbére (nílé ayé).
كَلَّا ۖ لَيُنۢبَذَنَّ فِى ٱلْحُطَمَةِ ﴿٤﴾
104:4Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀). Dájúdájú wọ́n máa kù ú lókò sínú Hutọmọh ni.
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا ٱلْحُطَمَةُ ﴿٥﴾
104:5Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Hutọmọh?
نَارُ ٱللَّهِ ٱلْمُوقَدَةُ ﴿٦﴾
104:6(Òhun ni) Iná Allāhu tí wọ́n ń kò (tó ń jó geregere),
ٱلَّتِى تَطَّلِعُ عَلَى ٱلْأَفْـِٔدَةِ ﴿٧﴾
104:7èyí tí ó máa jó (ẹ̀dá) wọ inú ọkàn lọ.
إِنَّهَا عَلَيْهِم مُّؤْصَدَةٌۭ ﴿٨﴾
104:8Dájúdájú wọ́n máa ti (àwọn ìlẹ̀kùn) Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.
فِى عَمَدٍۢ مُّمَدَّدَةٍۭ ﴿٩﴾
104:9(Wọ́n máa wà) láààrin àwọn òpó kìrìbìtì gíga (nínú Iná).
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni