ALMUDEEF TVQuran Channel

Read Quran

سُورَةُ القَدۡرِ

Suratul Al-Qadr · 5 ayahs

  1. بِّسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ إِنَّآ أَنزَلْنَٰهُ فِى لَيْلَةِ ٱلْقَدْرِ ﴿١﴾

    97:1Dájúdájú Àwa sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú Òru Abiyì.

  2. وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا لَيْلَةُ ٱلْقَدْرِ ﴿٢﴾

    97:2Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Òru Abiyì?

  3. لَيْلَةُ ٱلْقَدْرِ خَيْرٌۭ مِّنْ أَلْفِ شَهْرٍۢ ﴿٣﴾

    97:3Òru Abiyì lóore ju ẹgbẹ̀rún oṣù.

  4. تَنَزَّلُ ٱلْمَلَٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ فِيهَا بِإِذْنِ رَبِّهِم مِّن كُلِّ أَمْرٍۢ ﴿٤﴾

    97:4Àwọn mọlāika àti Jibrīl yó sì máa sọ̀kalẹ̀ nínú òru náà pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn fún gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan.

  5. سَلَٰمٌ هِىَ حَتَّىٰ مَطْلَعِ ٱلْفَجْرِ ﴿٥﴾

    97:5Àlàáfíà ni òru náà títí di àsìkò àfẹ̀mọ́júmọ́.

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni