Read Quran
سُورَةُ الرَّحۡمَٰن
Suratul Ar-Rahmaan · 78 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ ٱلرَّحْمَٰنُ ﴿١﴾
55:1Àjọkẹ́-ayé,
عَلَّمَ ٱلْقُرْءَانَ ﴿٢﴾
55:2Ó fi ìmọ̀ al-Ƙur’ān mọ (ẹni tí Ó fẹ́).
خَلَقَ ٱلْإِنسَٰنَ ﴿٣﴾
55:3Ó ṣẹ̀dá ènìyàn.
عَلَّمَهُ ٱلْبَيَانَ ﴿٤﴾
55:4Ó sì fi àlàyé (ọ̀rọ̀ sísọ) mọ̀ ọ́n.
ٱلشَّمْسُ وَٱلْقَمَرُ بِحُسْبَانٍۢ ﴿٥﴾
55:5Òòrùn àti òṣùpá (ń rìn) fún ìṣírò (ọjọ́ ayé).
وَٱلنَّجْمُ وَٱلشَّجَرُ يَسْجُدَانِ ﴿٦﴾
55:6Àwọn ìtàkùn ilẹ̀ àti igi ń forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).
وَٱلسَّمَآءَ رَفَعَهَا وَوَضَعَ ٱلْمِيزَانَ ﴿٧﴾
55:7Àti sánmọ̀, Allāhu gbé e sókè. Ó sì fi òṣùwọ̀n òfin déédé lélẹ̀ (fún ẹ̀dá)
أَلَّا تَطْغَوْا۟ فِى ٱلْمِيزَانِ ﴿٨﴾
55:8pé kí ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà níbi òṣùwọ̀n.
وَأَقِيمُوا۟ ٱلْوَزْنَ بِٱلْقِسْطِ وَلَا تُخْسِرُوا۟ ٱلْمِيزَانَ ﴿٩﴾
55:9Ẹ gbé òṣùwọ̀n náà dúró pẹ̀lú dọ́gbadọ́gba. Kí ẹ sì má ṣe dín òṣùwọ̀n kù.
وَٱلْأَرْضَ وَضَعَهَا لِلْأَنَامِ ﴿١٠﴾
55:10Ilẹ̀, (Allāhu) gbé e kalẹ̀ (sí abẹ́ sánmọ̀ fún àwọn ẹ̀dá.
فِيهَا فَٰكِهَةٌۭ وَٱلنَّخْلُ ذَاتُ ٱلْأَكْمَامِ ﴿١١﴾
55:11Èso àti dàbínù alápó wà lórí (ilẹ̀).
وَٱلْحَبُّ ذُو ٱلْعَصْفِ وَٱلرَّيْحَانُ ﴿١٢﴾
55:12Àti èso onípòpórò àti olóòórùn dídùn (wà lórí ilẹ̀).
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿١٣﴾
55:13Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
خَلَقَ ٱلْإِنسَٰنَ مِن صَلْصَٰلٍۢ كَٱلْفَخَّارِ ﴿١٤﴾
55:14(Allāhu) ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ gbígbẹ tó ń dún kokoko bí ìkòkò amọ̀.
وَخَلَقَ ٱلْجَآنَّ مِن مَّارِجٍۢ مِّن نَّارٍۢ ﴿١٥﴾
55:15Ó sì ṣẹ̀dá àlùjànnú láti ara ahọ́n iná tí kò ní èéfín.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿١٦﴾
55:16Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
رَبُّ ٱلْمَشْرِقَيْنِ وَرَبُّ ٱلْمَغْرِبَيْنِ ﴿١٧﴾
55:17Olúwa ibùyọ òòrùn méjèèjì àti ibùwọ̀ òòrùn méjèèjì.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿١٨﴾
55:18Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
مَرَجَ ٱلْبَحْرَيْنِ يَلْتَقِيَانِ ﴿١٩﴾
55:19(Allāhu) mú odò méjì (odò oníyọ̀ àti odò aládùn) ṣàn pàdé ara wọn.
بَيْنَهُمَا بَرْزَخٌۭ لَّا يَبْغِيَانِ ﴿٢٠﴾
55:20Gàgá kan sì wà láààrin àwọn méjèèjì tí wọn kò sì lè tayọ ẹnu-ààlà (rẹ̀ láààrin ara wọn).
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٢١﴾
55:21Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
يَخْرُجُ مِنْهُمَا ٱللُّؤْلُؤُ وَٱلْمَرْجَانُ ﴿٢٢﴾
55:22Òkúta oníyebíye àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn ń jáde nínú àwọn (odò) méjèèjì náà.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٢٣﴾
55:23Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
وَلَهُ ٱلْجَوَارِ ٱلْمُنشَـَٔاتُ فِى ٱلْبَحْرِ كَٱلْأَعْلَٰمِ ﴿٢٤﴾
55:24Ti (Allāhu) ni àwọn ọkọ̀ ojú-omi gogoro tó ń rìn nínú agbami òdò (tí wọ́n dà) bí àpáta gíga.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٢٥﴾
55:25Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
كُلُّ مَنْ عَلَيْهَا فَانٍۢ ﴿٢٦﴾
55:26Gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ máa tán.
وَيَبْقَىٰ وَجْهُ رَبِّكَ ذُو ٱلْجَلَٰلِ وَٱلْإِكْرَامِ ﴿٢٧﴾
55:27Ojú Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé sì máa wà títí láéláé.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٢٨﴾
55:28Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
يَسْـَٔلُهُۥ مَن فِى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ ۚ كُلَّ يَوْمٍ هُوَ فِى شَأْنٍۢ ﴿٢٩﴾
55:29Àwọn tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ń bèèrè (n̄ǹkan) lọ́dọ̀ Rẹ̀; Ó sì wà lórí ìṣe lójoojúmọ́.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٣٠﴾
55:30Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
سَنَفْرُغُ لَكُمْ أَيُّهَ ٱلثَّقَلَانِ ﴿٣١﴾
55:31A óò mú tiyín gbọ́ (lọ́jọ́ ẹ̀san), ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٣٢﴾
55:32Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
يَٰمَعْشَرَ ٱلْجِنِّ وَٱلْإِنسِ إِنِ ٱسْتَطَعْتُمْ أَن تَنفُذُوا۟ مِنْ أَقْطَارِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلْأَرْضِ فَٱنفُذُوا۟ ۚ لَا تَنفُذُونَ إِلَّا بِسُلْطَٰنٍۢ ﴿٣٣﴾
55:33Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú àti ènìyàn, tí ẹ bá lágbára láti sá jáde nínú àwọn agbègbè sánmọ̀ àti ilẹ̀, ẹ sá jáde. Ẹ kò lè sá jáde àfi pẹ̀lú agbára.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٣٤﴾
55:34Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
يُرْسَلُ عَلَيْكُمَا شُوَاظٌۭ مِّن نَّارٍۢ وَنُحَاسٌۭ فَلَا تَنتَصِرَانِ ﴿٣٥﴾
55:35Wọ́n máa ju ahọ́n iná àti èéfín (tàbí oje idẹ) iná lé ẹ̀yin méjèèjì lórí, ẹ̀yin méjèèjì kò sì níí lè ranra yín lọ́wọ́.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٣٦﴾
55:36Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
فَإِذَا ٱنشَقَّتِ ٱلسَّمَآءُ فَكَانَتْ وَرْدَةًۭ كَٱلدِّهَانِ ﴿٣٧﴾
55:37Nítorí náà, nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì máa pọ́n wá wẹ̀ bí epo pupa gbígbá.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٣٨﴾
55:38Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
فَيَوْمَئِذٍۢ لَّا يُسْـَٔلُ عَن ذَنۢبِهِۦٓ إِنسٌۭ وَلَا جَآنٌّۭ ﴿٣٩﴾
55:39Nítorí náà, ní ọjọ́ yẹn Wọn kò níí bi ènìyàn àti àlùjànnú kan léèrè nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; (ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Wa).
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٤٠﴾
55:40Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
يُعْرَفُ ٱلْمُجْرِمُونَ بِسِيمَٰهُمْ فَيُؤْخَذُ بِٱلنَّوَٰصِى وَٱلْأَقْدَامِ ﴿٤١﴾
55:41Wọ́n máa dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ̀ pẹ̀lú àmì ara wọn. Wọ́n sì máa fi àásó orí àti ẹsẹ̀ gbá wọn mú.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٤٢﴾
55:42Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
هَٰذِهِۦ جَهَنَّمُ ٱلَّتِى يُكَذِّبُ بِهَا ٱلْمُجْرِمُونَ ﴿٤٣﴾
55:43Èyí ni iná Jahanamọ tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń pè ní irọ́.
يَطُوفُونَ بَيْنَهَا وَبَيْنَ حَمِيمٍ ءَانٍۢ ﴿٤٤﴾
55:44Wọn yóò máa rìn lọ rìn bọ̀ láààrin Iná àti omi tó gbóná parí.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٤٥﴾
55:45Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
وَلِمَنْ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِۦ جَنَّتَانِ ﴿٤٦﴾
55:46Ọgbà Ìdẹ̀ra méjì ń bẹ fún ẹni tó bá páyà ìdúró rẹ̀ níwájú Olúwa rẹ̀.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٤٧﴾
55:47Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
ذَوَاتَآ أَفْنَانٍۢ ﴿٤٨﴾
55:48(Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra méjèèjì ní) àwọn ẹ̀ka igi tó kún fún àwọn èso oríṣiríṣi.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٤٩﴾
55:49Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
فِيهِمَا عَيْنَانِ تَجْرِيَانِ ﴿٥٠﴾
55:50Odò méjì tó ń ṣàn wà nínú ọgbà méjèèjì.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٥١﴾
55:51Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
فِيهِمَا مِن كُلِّ فَٰكِهَةٍۢ زَوْجَانِ ﴿٥٢﴾
55:52Oríṣi méjì méjì ni èso kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ọgbà méjèèjì.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٥٣﴾
55:53Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
مُتَّكِـِٔينَ عَلَىٰ فُرُشٍۭ بَطَآئِنُهَا مِنْ إِسْتَبْرَقٍۢ ۚ وَجَنَى ٱلْجَنَّتَيْنِ دَانٍۢ ﴿٥٤﴾
55:54Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí ìtẹ́, tí àwọn ìtẹ́ inú rẹ̀ jẹ́ àrán tó nípọn. Àwọn èso ọgbà méjèèjì sì wà ní àrọ́wọ́tó.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٥٥﴾
55:55Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
فِيهِنَّ قَٰصِرَٰتُ ٱلطَّرْفِ لَمْ يَطْمِثْهُنَّ إِنسٌۭ قَبْلَهُمْ وَلَا جَآنٌّۭ ﴿٥٦﴾
55:56Àwọn obìnrin tí kì í wo ọkùnrin mìíràn wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò sì fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٥٧﴾
55:57Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
كَأَنَّهُنَّ ٱلْيَاقُوتُ وَٱلْمَرْجَانُ ﴿٥٨﴾
55:58Wọ́n dà bíi ìlẹ̀kẹ̀ ṣẹ̀gi àti ìlẹ̀kẹ̀ iyùn (nípa ẹwà àti dídára wọn).
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٥٩﴾
55:59Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
هَلْ جَزَآءُ ٱلْإِحْسَٰنِ إِلَّا ٱلْإِحْسَٰنُ ﴿٦٠﴾
55:60Ǹjẹ́ ẹ̀san mìíràn wà fún ṣíṣe rere bí kò ṣe (ẹ̀san) rere.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٦١﴾
55:61Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
وَمِن دُونِهِمَا جَنَّتَانِ ﴿٦٢﴾
55:62Ọgbà Ìdẹ̀ra méjì kan tún ń bẹ yàtọ̀ sí méjì (àkọ́kọ́ yẹn).
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٦٣﴾
55:63Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
مُدْهَآمَّتَانِ ﴿٦٤﴾
55:64Aláwọ̀ ewéko (ni Ọgbà méjèèjì náà).
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٦٥﴾
55:65Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
فِيهِمَا عَيْنَانِ نَضَّاخَتَانِ ﴿٦٦﴾
55:66Àwọn odò méjì tó ń tú omi jáde láì dáwọ́ dúró wà (nínú ọgbà méjèèjì náà).
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٦٧﴾
55:67Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
فِيهِمَا فَٰكِهَةٌۭ وَنَخْلٌۭ وَرُمَّانٌۭ ﴿٦٨﴾
55:68Èso ìpanu, dàbínù àti èso rumọ̄n wà nínú ọgbà méjèèjì náà.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٦٩﴾
55:69Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
فِيهِنَّ خَيْرَٰتٌ حِسَانٌۭ ﴿٧٠﴾
55:70Àwọn obìnrin rere, arẹwà wà nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra náà.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٧١﴾
55:71Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
حُورٌۭ مَّقْصُورَٰتٌۭ فِى ٱلْخِيَامِ ﴿٧٢﴾
55:72Àwọn ẹlẹ́yinjú-ẹgẹ́ kan (ni wọ́n), tí A fi pamọ́ sínú ilé-ọ̀ṣọ́.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٧٣﴾
55:73Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
لَمْ يَطْمِثْهُنَّ إِنسٌۭ قَبْلَهُمْ وَلَا جَآنٌّۭ ﴿٧٤﴾
55:74Ènìyàn àti àlùjànnú kan kò fọwọ́ kàn wọ́n rí ṣíwájú wọn.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٧٥﴾
55:75Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
مُتَّكِـِٔينَ عَلَىٰ رَفْرَفٍ خُضْرٍۢ وَعَبْقَرِىٍّ حِسَانٍۢ ﴿٧٦﴾
55:76Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú lórí àwọn tìmùtìmù aláwọ̀ ewéko àti ìtẹ́ tó dára.
فَبِأَىِّ ءَالَآءِ رَبِّكُمَا تُكَذِّبَانِ ﴿٧٧﴾
55:77Nítorí náà, èwo nínú àwọn ìdẹ̀ra Olúwa ẹ̀yin ènìyàn àti àlùjànnú ni ẹ máa pè ní irọ́?
تَبَٰرَكَ ٱسْمُ رَبِّكَ ذِى ٱلْجَلَٰلِ وَٱلْإِكْرَامِ ﴿٧٨﴾
55:78Ìbùkún ni fún orúkọ Olúwa rẹ, Atóbi, Alápọ̀n-ọ́nlé.
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni