Read Quran
سُورَةُ الطَّارِقِ
Suratul At-Taariq · 17 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلسَّمَآءِ وَٱلطَّارِقِ ﴿١﴾
86:1(Allāhu) fi sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ búra.
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا ٱلطَّارِقُ ﴿٢﴾
86:2Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Tọ̄riƙ?
ٱلنَّجْمُ ٱلثَّاقِبُ ﴿٣﴾
86:3Ìràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni).
إِن كُلُّ نَفْسٍۢ لَّمَّا عَلَيْهَا حَافِظٌۭ ﴿٤﴾
86:4Kò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika).
فَلْيَنظُرِ ٱلْإِنسَٰنُ مِمَّ خُلِقَ ﴿٥﴾
86:5Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí ohun tí A fi ṣẹ̀dá rẹ̀.
خُلِقَ مِن مَّآءٍۢ دَافِقٍۢ ﴿٦﴾
86:6Wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú omi tó ń tú jáde kọ̀ọ́kọ̀ọ́.
يَخْرُجُ مِنۢ بَيْنِ ٱلصُّلْبِ وَٱلتَّرَآئِبِ ﴿٧﴾
86:7Ó ń jáde láti ààrin ìbàdí ọkùnrin àti àwọn ẹfọ́nhà igbá-àyà obìnrin.
إِنَّهُۥ عَلَىٰ رَجْعِهِۦ لَقَادِرٌۭ ﴿٨﴾
86:8Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lóri ìdápadà rẹ̀
يَوْمَ تُبْلَى ٱلسَّرَآئِرُ ﴿٩﴾
86:9ní ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò àwọn (iṣẹ́) àṣepamọ́.
فَمَا لَهُۥ مِن قُوَّةٍۢ وَلَا نَاصِرٍۢ ﴿١٠﴾
86:10Nígbà náà, kò níí sí agbára tàbí alárànṣe kan fún un.
وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلرَّجْعِ ﴿١١﴾
86:11Allāhu fi sánmọ̀ tó ń rọ òjò ní ọdọọdún búra.
وَٱلْأَرْضِ ذَاتِ ٱلصَّدْعِ ﴿١٢﴾
86:12Ó tún fi ilẹ̀ tó ń sán kànkàn (fún híhùjáde èso) búra.
إِنَّهُۥ لَقَوْلٌۭ فَصْلٌۭ ﴿١٣﴾
86:13Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀-ìpínyà (láààrin òdodo àti irọ́).
وَمَا هُوَ بِٱلْهَزْلِ ﴿١٤﴾
86:14Kì í sì ṣe àwàdà.
إِنَّهُمْ يَكِيدُونَ كَيْدًۭا ﴿١٥﴾
86:15Dájúdájú wọ́n ń déte gan-an.
وَأَكِيدُ كَيْدًۭا ﴿١٦﴾
86:16Èmi náà sì ń déte gan-an.
فَمَهِّلِ ٱلْكَٰفِرِينَ أَمْهِلْهُمْ رُوَيْدًۢا ﴿١٧﴾
86:17Nítorí náà, lọ́ra fún àwọn aláìgbàgbọ́. Lọ́ wọn lára sẹ́ fún ìgbà díẹ̀.
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni