Read Quran
سُورَةُ العَادِيَاتِ
Suratul Al-Aadiyaat · 11 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلْعَٰدِيَٰتِ ضَبْحًۭا ﴿١﴾
100:1Allāhu fi àwọn ẹṣin tó ń sáré tó ń mí hẹlẹhẹlẹ ní ojú-ogun búra.
فَٱلْمُورِيَٰتِ قَدْحًۭا ﴿٢﴾
100:2Ó tún fi àwọn ẹṣin tí pátákò ẹsẹ̀ wọn ń ṣáná (níbi eré sísá) búra.
فَٱلْمُغِيرَٰتِ صُبْحًۭا ﴿٣﴾
100:3Ó tún fi àwọn ẹṣin tó ń kọlu ọ̀tá ẹ̀sìn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù búra.
فَأَثَرْنَ بِهِۦ نَقْعًۭا ﴿٤﴾
100:4Wọ́n sì fi (pátákò ẹsẹ̀ wọn) tu eruku (ilẹ̀ ọ̀tá) sókè.
فَوَسَطْنَ بِهِۦ جَمْعًا ﴿٥﴾
100:5Wọ́n tún bẹ́ gìjà pẹ̀lú eruku ẹsẹ̀ wọn sáààrin àkójọ ọ̀tá.
إِنَّ ٱلْإِنسَٰنَ لِرَبِّهِۦ لَكَنُودٌۭ ﴿٦﴾
100:6Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore sí Olúwa rẹ̀.
وَإِنَّهُۥ عَلَىٰ ذَٰلِكَ لَشَهِيدٌۭ ﴿٧﴾
100:7Dájúdájú Allāhu sì ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.
وَإِنَّهُۥ لِحُبِّ ٱلْخَيْرِ لَشَدِيدٌ ﴿٨﴾
100:8Àti pé dájúdájú ènìyàn le gan-an níbi ìfẹ́ oore ayé.
۞ أَفَلَا يَعْلَمُ إِذَا بُعْثِرَ مَا فِى ٱلْقُبُورِ ﴿٩﴾
100:9Ṣé kò mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá tú ohun tó wà nínú sàréè jáde (fún àjíǹde),
وَحُصِّلَ مَا فِى ٱلصُّدُورِ ﴿١٠﴾
100:10tí wọ́n sì tú ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá síta pátápátá,
إِنَّ رَبَّهُم بِهِمْ يَوْمَئِذٍۢ لَّخَبِيرٌۢ ﴿١١﴾
100:11dájúdájú Olúwa wọn ni Alámọ̀tán nípa wọn ní Ọjọ́ yẹn?
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni