Read Quran
سُورَةُ الانفِطَارِ
Suratul Al-Infitaar · 19 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنفَطَرَتْ ﴿١﴾
82:1Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,
وَإِذَا ٱلْكَوَاكِبُ ٱنتَثَرَتْ ﴿٢﴾
82:2àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
وَإِذَا ٱلْبِحَارُ فُجِّرَتْ ﴿٣﴾
82:3àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,
وَإِذَا ٱلْقُبُورُ بُعْثِرَتْ ﴿٤﴾
82:4àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,
عَلِمَتْ نَفْسٌۭ مَّا قَدَّمَتْ وَأَخَّرَتْ ﴿٥﴾
82:5(nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).
يَٰٓأَيُّهَا ٱلْإِنسَٰنُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ ٱلْكَرِيمِ ﴿٦﴾
82:6Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé,
ٱلَّذِى خَلَقَكَ فَسَوَّىٰكَ فَعَدَلَكَ ﴿٧﴾
82:7Ẹni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn.
فِىٓ أَىِّ صُورَةٍۢ مَّا شَآءَ رَكَّبَكَ ﴿٨﴾
82:8Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́.
كَلَّا بَلْ تُكَذِّبُونَ بِٱلدِّينِ ﴿٩﴾
82:9Rárá! Bí kò ṣe pé ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.
وَإِنَّ عَلَيْكُمْ لَحَٰفِظِينَ ﴿١٠﴾
82:10Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín.
كِرَامًۭا كَٰتِبِينَ ﴿١١﴾
82:11(Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá.
يَعْلَمُونَ مَا تَفْعَلُونَ ﴿١٢﴾
82:12Wọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
إِنَّ ٱلْأَبْرَارَ لَفِى نَعِيمٍۢ ﴿١٣﴾
82:13Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn.
وَإِنَّ ٱلْفُجَّارَ لَفِى جَحِيمٍۢ ﴿١٤﴾
82:14Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm.
يَصْلَوْنَهَا يَوْمَ ٱلدِّينِ ﴿١٥﴾
82:15Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san.
وَمَا هُمْ عَنْهَا بِغَآئِبِينَ ﴿١٦﴾
82:16Wọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀.
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا يَوْمُ ٱلدِّينِ ﴿١٧﴾
82:17Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?
ثُمَّ مَآ أَدْرَىٰكَ مَا يَوْمُ ٱلدِّينِ ﴿١٨﴾
82:18Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?
يَوْمَ لَا تَمْلِكُ نَفْسٌۭ لِّنَفْسٍۢ شَيْـًۭٔا ۖ وَٱلْأَمْرُ يَوْمَئِذٍۢ لِّلَّهِ ﴿١٩﴾
82:19(Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu.
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni