Read Quran
سُورَةُ المَسَدِ
Suratul Al-Masad · 5 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ تَبَّتْ يَدَآ أَبِى لَهَبٍۢ وَتَبَّ ﴿١﴾
111:1Ọwọ́ Abu-Lahab méjèèjì ti ṣòfò. Òun náà sì ṣòfò.
مَآ أَغْنَىٰ عَنْهُ مَالُهُۥ وَمَا كَسَبَ ﴿٢﴾
111:2Àwọn dúkìá rẹ̀ àti ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (ìyẹn, àwọn ọmọ rẹ̀) kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ (níbi ìyà).
سَيَصْلَىٰ نَارًۭا ذَاتَ لَهَبٍۢ ﴿٣﴾
111:3Ó sì máa wọ inú Iná eléjò fòfò.
وَٱمْرَأَتُهُۥ حَمَّالَةَ ٱلْحَطَبِ ﴿٤﴾
111:4Àti ìyàwó rẹ̀, aláàárù-igi-ìṣẹ́pẹ́ ẹlẹ́gùn-ún, (ó máa wọná).
فِى جِيدِهَا حَبْلٌۭ مِّن مَّسَدٍۭ ﴿٥﴾
111:5Igbà-ọ̀pẹ pọ̀npọ̀nràn máa wà ní ọrùn rẹ̀ (nínú Iná).
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni