Read Quran
سُورَةُ عَبَسَ
Suratul Abasa · 42 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ عَبَسَ وَتَوَلَّىٰٓ ﴿١﴾
80:1Ó fajú ro, ó sì pẹ̀yìndà
أَن جَآءَهُ ٱلْأَعْمَىٰ ﴿٢﴾
80:2nítorí pé afọ́jú wá bá a.
وَمَا يُدْرِيكَ لَعَلَّهُۥ يَزَّكَّىٰٓ ﴿٣﴾
80:3Kí sì l’ó máa fi mọ̀ ọ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó ṣàfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́)
أَوْ يَذَّكَّرُ فَتَنفَعَهُ ٱلذِّكْرَىٰٓ ﴿٤﴾
80:4tàbí kí ó gbọ́ ìrántí, kí ìrántí náà sì ṣe é ní àǹfààní?
أَمَّا مَنِ ٱسْتَغْنَىٰ ﴿٥﴾
80:5Ní ti ẹni tí ó ka ara rẹ̀ kún ọlọ́rọ̀,
فَأَنتَ لَهُۥ تَصَدَّىٰ ﴿٦﴾
80:6òun ni ìwọ tẹ́tí sí.
وَمَا عَلَيْكَ أَلَّا يَزَّكَّىٰ ﴿٧﴾
80:7Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ bí kò bá ṣe àfọ̀mọ́ (ara rẹ̀ kúrò nínú àìgbàgbọ́).
وَأَمَّا مَن جَآءَكَ يَسْعَىٰ ﴿٨﴾
80:8Ní ti ẹni tí ó sì wá bá ọ, tó ń yára gágá (sí ìrántí, ìyẹn afọ́jú),
وَهُوَ يَخْشَىٰ ﴿٩﴾
80:9tí ó sì ń páyà (Allāhu),
فَأَنتَ عَنْهُ تَلَهَّىٰ ﴿١٠﴾
80:10ìwọ kò sì kọbi ara sí i.
كَلَّآ إِنَّهَا تَذْكِرَةٌۭ ﴿١١﴾
80:11Rárá (kò tọ́ bẹ́ẹ̀). Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí.
فَمَن شَآءَ ذَكَرَهُۥ ﴿١٢﴾
80:12Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó rántí rẹ̀.
فِى صُحُفٍۢ مُّكَرَّمَةٍۢ ﴿١٣﴾
80:13(Al-Ƙur’ān) wà nínú àwọn tàkádà alápọ̀n-ọ́nlé,
مَّرْفُوعَةٍۢ مُّطَهَّرَةٍۭ ﴿١٤﴾
80:14A gbé e ga, A sì ṣe é ní mímọ́
بِأَيْدِى سَفَرَةٍۢ ﴿١٥﴾
80:15ní ọwọ́ àwọn òǹkọtíà (ìyẹn, àwọn mọlāika),
كِرَامٍۭ بَرَرَةٍۢ ﴿١٦﴾
80:16àwọn alápọ̀n-ọ́nlé, àwọn ẹni rere.
قُتِلَ ٱلْإِنسَٰنُ مَآ أَكْفَرَهُۥ ﴿١٧﴾
80:17Wọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ!
مِنْ أَىِّ شَىْءٍ خَلَقَهُۥ ﴿١٨﴾
80:18Kí sì ni Allāhu fi ṣẹ̀dá rẹ̀?
مِن نُّطْفَةٍ خَلَقَهُۥ فَقَدَّرَهُۥ ﴿١٩﴾
80:19Nínú àtọ̀ l’Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀.
ثُمَّ ٱلسَّبِيلَ يَسَّرَهُۥ ﴿٢٠﴾
80:20Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un.
ثُمَّ أَمَاتَهُۥ فَأَقْبَرَهُۥ ﴿٢١﴾
80:21Lẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè.
ثُمَّ إِذَا شَآءَ أَنشَرَهُۥ ﴿٢٢﴾
80:22Lẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde.
كَلَّا لَمَّا يَقْضِ مَآ أَمَرَهُۥ ﴿٢٣﴾
80:23Rárá o! Ènìyàn kò tí ì ṣe n̄ǹkan tí Allāhu pa láṣẹ fún un.
فَلْيَنظُرِ ٱلْإِنسَٰنُ إِلَىٰ طَعَامِهِۦٓ ﴿٢٤﴾
80:24Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí oúnjẹ rẹ̀.
أَنَّا صَبَبْنَا ٱلْمَآءَ صَبًّۭا ﴿٢٥﴾
80:25Dájúdájú Àwa ń rọ òjò ní púpọ̀.
ثُمَّ شَقَقْنَا ٱلْأَرْضَ شَقًّۭا ﴿٢٦﴾
80:26Lẹ́yìn náà, A mú ilẹ̀ sán kànkàn.
فَأَنۢبَتْنَا فِيهَا حَبًّۭا ﴿٢٧﴾
80:27A sì mú kóró èso hù jáde láti inú rẹ̀;
وَعِنَبًۭا وَقَضْبًۭا ﴿٢٨﴾
80:28àti èso àjàrà àti kànnáfùrù,
وَزَيْتُونًۭا وَنَخْلًۭا ﴿٢٩﴾
80:29àti igi òróró Zaetūn àti dàbínù,
وَحَدَآئِقَ غُلْبًۭا ﴿٣٠﴾
80:30àti àwọn ọgbà tó kún fún igi,
وَفَٰكِهَةًۭ وَأَبًّۭا ﴿٣١﴾
80:31àti àwọn èso (mìíràn) pẹ̀lú ewé tí ẹranko ń jẹ, (A mú wọn hù jáde).
مَّتَٰعًۭا لَّكُمْ وَلِأَنْعَٰمِكُمْ ﴿٣٢﴾
80:32(Wọ́n jẹ́ n̄ǹkan) ìgbádùn fún ẹ̀yin àti àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.
فَإِذَا جَآءَتِ ٱلصَّآخَّةُ ﴿٣٣﴾
80:33Nígbà tí fífọn sínú ìwo nígbà kejì bá ṣẹlẹ̀,
يَوْمَ يَفِرُّ ٱلْمَرْءُ مِنْ أَخِيهِ ﴿٣٤﴾
80:34ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò sá fún arákùnrin rẹ̀,
وَأُمِّهِۦ وَأَبِيهِ ﴿٣٥﴾
80:35àti ìyá rẹ̀ àti bàbá rẹ̀,
وَصَٰحِبَتِهِۦ وَبَنِيهِ ﴿٣٦﴾
80:36àti ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀.
لِكُلِّ ٱمْرِئٍۢ مِّنْهُمْ يَوْمَئِذٍۢ شَأْنٌۭ يُغْنِيهِ ﴿٣٧﴾
80:37Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ọjọ́ yẹn l’ó ti ní ọ̀ràn tó máa tó o ó rán.
وُجُوهٌۭ يَوْمَئِذٍۢ مُّسْفِرَةٌۭ ﴿٣٨﴾
80:38Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn yóò mọ́lẹ̀.
ضَاحِكَةٌۭ مُّسْتَبْشِرَةٌۭ ﴿٣٩﴾
80:39Wọn yó máa rẹ́rìn-ín, wọn yó sì máa dunnú.
وَوُجُوهٌۭ يَوْمَئِذٍ عَلَيْهَا غَبَرَةٌۭ ﴿٤٠﴾
80:40Àwọn ojú kan lọ́jọ́ yẹn ni eruku yó sì bò mọ́lẹ̀.
تَرْهَقُهَا قَتَرَةٌ ﴿٤١﴾
80:41Òkùnkùn yó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀.
أُو۟لَٰٓئِكَ هُمُ ٱلْكَفَرَةُ ٱلْفَجَرَةُ ﴿٤٢﴾
80:42Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni