ALMUDEEF TVQuran Channel

Read Quran

سُورَةُ الانشِقَاقِ

Suratul Al-Inshiqaaq · 25 ayahs

  1. بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنشَقَّتْ ﴿١﴾

    84:1Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ

  2. وَأَذِنَتْ لِرَبِّهَا وَحُقَّتْ ﴿٢﴾

    84:2- ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀-

  3. وَإِذَا ٱلْأَرْضُ مُدَّتْ ﴿٣﴾

    84:3àti nígbà tí A bá fẹ ilẹ̀ lójú,

  4. وَأَلْقَتْ مَا فِيهَا وَتَخَلَّتْ ﴿٤﴾

    84:4ó máa ju ohun tí ó wà nínú rẹ̀ síta, ó sì máa pa sófo

  5. وَأَذِنَتْ لِرَبِّهَا وَحُقَّتْ ﴿٥﴾

    84:5- ó gbọ́, ó sì tẹ̀lé àṣẹ Olúwa rẹ̀ ni. Ó sì di dandan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ - (ní ọjọ́ yẹn ni ẹ̀dá máa rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀)

  6. يَٰٓأَيُّهَا ٱلْإِنسَٰنُ إِنَّكَ كَادِحٌ إِلَىٰ رَبِّكَ كَدْحًۭا فَمُلَٰقِيهِ ﴿٦﴾

    84:6Ìwọ ènìyàn dájúdájú ìwọ ń ṣe iṣẹ́ kárakára ní iṣẹ́ àṣepàdé Olúwa rẹ. O sì máa mú un pàdé Rẹ̀.

  7. فَأَمَّا مَنْ أُوتِىَ كِتَٰبَهُۥ بِيَمِينِهِۦ ﴿٧﴾

    84:7Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀,

  8. فَسَوْفَ يُحَاسَبُ حِسَابًۭا يَسِيرًۭا ﴿٨﴾

    84:8láìpẹ́ A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ (rẹ̀) ní ìṣírò ìrọ̀rùn.

  9. وَيَنقَلِبُ إِلَىٰٓ أَهْلِهِۦ مَسْرُورًۭا ﴿٩﴾

    84:9Ó sì máa padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra) lẹ́ni ìdùnnú.

  10. وَأَمَّا مَنْ أُوتِىَ كِتَٰبَهُۥ وَرَآءَ ظَهْرِهِۦ ﴿١٠﴾

    84:10Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní ìwé iṣẹ́ rẹ̀ láti ẹ̀yìn rẹ̀,

  11. فَسَوْفَ يَدْعُوا۟ ثُبُورًۭا ﴿١١﴾

    84:11láìpẹ́ ó máa kígbe ìparun.

  12. وَيَصْلَىٰ سَعِيرًا ﴿١٢﴾

    84:12Ó sì máa wọ inú Iná tó ń jó.

  13. إِنَّهُۥ كَانَ فِىٓ أَهْلِهِۦ مَسْرُورًا ﴿١٣﴾

    84:13Dájúdájú ó ti wà láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́ni ìdùnnú (sí àìgbàgbọ́ nílé ayé).

  14. إِنَّهُۥ ظَنَّ أَن لَّن يَحُورَ ﴿١٤﴾

    84:14Dájúdájú ó lérò pé òun kò níí padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni).

  15. بَلَىٰٓ إِنَّ رَبَّهُۥ كَانَ بِهِۦ بَصِيرًۭا ﴿١٥﴾

    84:15Bẹ́ẹ̀ ni, (ó máa padà). Dájúdájú Olúwa rẹ̀ jẹ́ Olùríran nípa rẹ̀.

  16. فَلَآ أُقْسِمُ بِٱلشَّفَقِ ﴿١٦﴾

    84:16Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwòǹpapa búra.

  17. وَٱلَّيْلِ وَمَا وَسَقَ ﴿١٧﴾

    84:17Mo tún ń fi òru àti ohun tí ó kó jọ sínú rẹ̀ búra.

  18. وَٱلْقَمَرِ إِذَا ٱتَّسَقَ ﴿١٨﴾

    84:18Mo tún ń fi òṣùpá nígbà tí ó bá dégbá (tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kún) búra.

  19. لَتَرْكَبُنَّ طَبَقًا عَن طَبَقٍۢ ﴿١٩﴾

    84:19Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa bọ́ sínú wàhálà kan láti inú wàhálà kan.

  20. فَمَا لَهُمْ لَا يُؤْمِنُونَ ﴿٢٠﴾

    84:20Kí l’ó ṣe wọ́n ná tí wọn kò fi gbàgbọ́ ní òdodo?

  21. وَإِذَا قُرِئَ عَلَيْهِمُ ٱلْقُرْءَانُ لَا يَسْجُدُونَ ۩ ﴿٢١﴾

    84:21Nígbà tí wọ́n bá sì ké al-Ƙur’ān fún wọn, wọn kò níí forí kanlẹ̀.

  22. بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ يُكَذِّبُونَ ﴿٢٢﴾

    84:22Rárá, ńṣe ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń pè é ní irọ́.

  23. وَٱللَّهُ أَعْلَمُ بِمَا يُوعُونَ ﴿٢٣﴾

    84:23Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ (sínú ọkàn wọn).

  24. فَبَشِّرْهُم بِعَذَابٍ أَلِيمٍ ﴿٢٤﴾

    84:24Nítorí náà, fún wọn ní ìró ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

  25. إِلَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَعَمِلُوا۟ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُمْ أَجْرٌ غَيْرُ مَمْنُونٍۭ ﴿٢٥﴾

    84:25Àyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ẹ̀san tí kò níí pinń bẹ fún wọn.

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni