Read Quran
سُورَةُ المُرۡسَلَاتِ
Suratul Al-Mursalaat · 50 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ وَٱلْمُرْسَلَٰتِ عُرْفًۭا ﴿١﴾
77:1Allāhu fi àwọn atẹ́gùn tó ń sáré ní tẹ̀léǹtẹ̀lé búra.
فَٱلْعَٰصِفَٰتِ عَصْفًۭا ﴿٢﴾
77:2Ó fi àwọn ìjì atẹ́gùn tó ń jà búra.
وَٱلنَّٰشِرَٰتِ نَشْرًۭا ﴿٣﴾
77:3Ó fi àwọn atẹ́gùn tó ń tú èṣújò ká búra.
فَٱلْفَٰرِقَٰتِ فَرْقًۭا ﴿٤﴾
77:4Ó fi àwọn tó ń ṣèpínyà láààrin òdodo àti irọ́ búra.
فَٱلْمُلْقِيَٰتِ ذِكْرًا ﴿٥﴾
77:5Ó fi àwọn mọlāika tó ń mú ìrántí wá (bá àwọn Òjíṣẹ́) búra.
عُذْرًا أَوْ نُذْرًا ﴿٦﴾
77:6(Ìrántí náà jẹ́) àwíjàre tàbí ìkìlọ̀.
إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَوَٰقِعٌۭ ﴿٧﴾
77:7Dájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fún yín kúkú máa ṣẹlẹ̀.
فَإِذَا ٱلنُّجُومُ طُمِسَتْ ﴿٨﴾
77:8Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́,
وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ فُرِجَتْ ﴿٩﴾
77:9àti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada,
وَإِذَا ٱلْجِبَالُ نُسِفَتْ ﴿١٠﴾
77:10àti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù,
وَإِذَا ٱلرُّسُلُ أُقِّتَتْ ﴿١١﴾
77:11àti nígbà tí wọ́n bá fún àwọn Òjíṣẹ́ ní àsìkò láti kójọ (pẹ̀lú ìjọ wọn),
لِأَىِّ يَوْمٍ أُجِّلَتْ ﴿١٢﴾
77:12ọjọ́ wo ni wọ́n so (àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí) rọ̀ fún ná?
لِيَوْمِ ٱلْفَصْلِ ﴿١٣﴾
77:13Fún ọjọ́ ìpínyà (láààrin àwọn ẹ̀dá) ni.
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا يَوْمُ ٱلْفَصْلِ ﴿١٤﴾
77:14Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ìpínyà?
وَيْلٌۭ يَوْمَئِذٍۢ لِّلْمُكَذِّبِينَ ﴿١٥﴾
77:15Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
أَلَمْ نُهْلِكِ ٱلْأَوَّلِينَ ﴿١٦﴾
77:16Ǹjẹ́ Àwa kò ti pa àwọn ẹni àkọ́kọ́ rẹ́ bí?
ثُمَّ نُتْبِعُهُمُ ٱلْءَاخِرِينَ ﴿١٧﴾
77:17Lẹ́yìn náà, A sì máa fi àwọn ẹni Ìkẹ́yìn tẹ̀lé wọn (nínú ìparun).
كَذَٰلِكَ نَفْعَلُ بِٱلْمُجْرِمِينَ ﴿١٨﴾
77:18Báyẹn ni A ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
وَيْلٌۭ يَوْمَئِذٍۢ لِّلْمُكَذِّبِينَ ﴿١٩﴾
77:19Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
أَلَمْ نَخْلُقكُّم مِّن مَّآءٍۢ مَّهِينٍۢ ﴿٢٠﴾
77:20Ṣé A kò ṣẹ̀dá yin láti inú omi lílẹ yẹpẹrẹ bí?
فَجَعَلْنَٰهُ فِى قَرَارٍۢ مَّكِينٍ ﴿٢١﴾
77:21Lẹ́yìn náà, A fi sínú àyè ààbò (ìyẹn, ilé-ọmọ)
إِلَىٰ قَدَرٍۢ مَّعْلُومٍۢ ﴿٢٢﴾
77:22títí di gbèdéke àkókò kan tí A ti mọ̀ (ìyen, ọjọ́ ìbímọ).
فَقَدَرْنَا فَنِعْمَ ٱلْقَٰدِرُونَ ﴿٢٣﴾
77:23A sì ní ìkápá àti àyànmọ́ (lórí rẹ̀. Àwa sì ni) Olùkápá àti Olùpèbùbù ẹ̀dá tó dára.
وَيْلٌۭ يَوْمَئِذٍۢ لِّلْمُكَذِّبِينَ ﴿٢٤﴾
77:24Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
أَلَمْ نَجْعَلِ ٱلْأَرْضَ كِفَاتًا ﴿٢٥﴾
77:25Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ohun tó ń kó ẹ̀dá jọ mọ́ra wọn;
أَحْيَآءًۭ وَأَمْوَٰتًۭا ﴿٢٦﴾
77:26(ìyẹn) àwọn alààyè àti àwọn òkú?
وَجَعَلْنَا فِيهَا رَوَٰسِىَ شَٰمِخَٰتٍۢ وَأَسْقَيْنَٰكُم مَّآءًۭ فُرَاتًۭا ﴿٢٧﴾
77:27A sì fi àwọn àpáta gbagidi gíga-gíga sínú rẹ̀. A sì fún yín ní omi dídùn mu.
وَيْلٌۭ يَوْمَئِذٍۢ لِّلْمُكَذِّبِينَ ﴿٢٨﴾
77:28Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
ٱنطَلِقُوٓا۟ إِلَىٰ مَا كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ ﴿٢٩﴾
77:29Ẹ máa lọ sí ibi tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.
ٱنطَلِقُوٓا۟ إِلَىٰ ظِلٍّۢ ذِى ثَلَٰثِ شُعَبٍۢ ﴿٣٠﴾
77:30Ẹ máa lọ sí ibi èéfín ẹlẹ́ka mẹ́ta.
لَّا ظَلِيلٍۢ وَلَا يُغْنِى مِنَ ٱللَّهَبِ ﴿٣١﴾
77:31Kì í ṣe ibòji tútù. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ìjòfòfò Iná.
إِنَّهَا تَرْمِى بِشَرَرٍۢ كَٱلْقَصْرِ ﴿٣٢﴾
77:32Dájúdájú (Iná náà) yóò máa ju ẹ̀tapàrà (rẹ̀ sókè tó máa dà) bí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì.
كَأَنَّهُۥ جِمَٰلَتٌۭ صُفْرٌۭ ﴿٣٣﴾
77:33(Ó máa dà) bí àwọn ràkúnmí aláwọ̀ omi ọsàn.
وَيْلٌۭ يَوْمَئِذٍۢ لِّلْمُكَذِّبِينَ ﴿٣٤﴾
77:34Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́
هَٰذَا يَوْمُ لَا يَنطِقُونَ ﴿٣٥﴾
77:35Èyí ni ọjọ́ tí wọn kò níí sọ̀rọ̀.
وَلَا يُؤْذَنُ لَهُمْ فَيَعْتَذِرُونَ ﴿٣٦﴾
77:36A kò sì níí yọ̀ǹda (ọ̀rọ̀ sísọ) fún wọn, áḿbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n yóò mú àwáwí wá.
وَيْلٌۭ يَوْمَئِذٍۢ لِّلْمُكَذِّبِينَ ﴿٣٧﴾
77:37Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
هَٰذَا يَوْمُ ٱلْفَصْلِ ۖ جَمَعْنَٰكُمْ وَٱلْأَوَّلِينَ ﴿٣٨﴾
77:38Èyí ni ọjọ́ ìpínyà. Àwa yó sì kó ẹ̀yin àti àwọn ẹni àkọ́kọ́ jọ.
فَإِن كَانَ لَكُمْ كَيْدٌۭ فَكِيدُونِ ﴿٣٩﴾
77:39Tí ẹ bá ní ète kan lọ́wọ́, ẹ déte sí Mi wò.
وَيْلٌۭ يَوْمَئِذٍۢ لِّلْمُكَذِّبِينَ ﴿٤٠﴾
77:40Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
إِنَّ ٱلْمُتَّقِينَ فِى ظِلَٰلٍۢ وَعُيُونٍۢ ﴿٤١﴾
77:41Dájúdájú àwọn olùbẹ̀rù Allāhu yóò wà níbi ibòji àti àwọn omi ìṣẹ́lẹ̀rú,
وَفَوَٰكِهَ مِمَّا يَشْتَهُونَ ﴿٤٢﴾
77:42àti àwọn èso èyí tí wọ́n bá ń fẹ́.
كُلُوا۟ وَٱشْرَبُوا۟ هَنِيٓـًٔۢا بِمَا كُنتُمْ تَعْمَلُونَ ﴿٤٣﴾
77:43Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbádùn nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجْزِى ٱلْمُحْسِنِينَ ﴿٤٤﴾
77:44Dájúdájú báyẹn ni Àwa ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).
وَيْلٌۭ يَوْمَئِذٍۢ لِّلْمُكَذِّبِينَ ﴿٤٥﴾
77:45Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
كُلُوا۟ وَتَمَتَّعُوا۟ قَلِيلًا إِنَّكُم مُّجْرِمُونَ ﴿٤٦﴾
77:46Ẹ jẹ, kí ẹ sì gbádùn fún ìgbà díẹ̀. Dájúdájú ẹlẹ́ṣẹ̀ ni yín.
وَيْلٌۭ يَوْمَئِذٍۢ لِّلْمُكَذِّبِينَ ﴿٤٧﴾
77:47Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱرْكَعُوا۟ لَا يَرْكَعُونَ ﴿٤٨﴾
77:48Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé kí wọ́n kírun, wọn kò níí kírun.
وَيْلٌۭ يَوْمَئِذٍۢ لِّلْمُكَذِّبِينَ ﴿٤٩﴾
77:49Ègbé ni ní ọjọ́ yẹn fún àwọn olùpe-òdodo-nírọ́.
فَبِأَىِّ حَدِيثٍۭ بَعْدَهُۥ يُؤْمِنُونَ ﴿٥٠﴾
77:50Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni