Read Quran
سُورَةُ القَارِعَةِ
Suratul Al-Qaari'a · 11 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ ٱلْقَارِعَةُ ﴿١﴾
101:1Àkókò ìjáyà.
مَا ٱلْقَارِعَةُ ﴿٢﴾
101:2Kí ni Àkókò ìjáyà?
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا ٱلْقَارِعَةُ ﴿٣﴾
101:3Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Àkókò ìjáyà?
يَوْمَ يَكُونُ ٱلنَّاسُ كَٱلْفَرَاشِ ٱلْمَبْثُوثِ ﴿٤﴾
101:4(Òhun ni) ọjọ́ tí ènìyàn yó dà bí àfòpiná tí wọ́n fọ́nká síta,
وَتَكُونُ ٱلْجِبَالُ كَٱلْعِهْنِ ٱلْمَنفُوشِ ﴿٥﴾
101:5àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú tí wọ́n gbọ̀n dànù.
فَأَمَّا مَن ثَقُلَتْ مَوَٰزِينُهُۥ ﴿٦﴾
101:6Nítorí náà, ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá tẹ̀wọ̀n,
فَهُوَ فِى عِيشَةٍۢ رَّاضِيَةٍۢ ﴿٧﴾
101:7ó sì máa wà nínú ìṣẹ̀mí tó máa yọ́nú sí.
وَأَمَّا مَنْ خَفَّتْ مَوَٰزِينُهُۥ ﴿٨﴾
101:8Ní ti ẹni tí òṣùwọ̀n (iṣẹ́ rere) rẹ̀ bá sì fúyẹ́,
فَأُمُّهُۥ هَاوِيَةٌۭ ﴿٩﴾
101:9Hāwiyah sì ni ibùgbé rẹ̀.
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا هِيَهْ ﴿١٠﴾
101:10Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀?
نَارٌ حَامِيَةٌۢ ﴿١١﴾
101:11(Òhun ni) Iná gbígbóná tó ń jó gan-an.
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni