ALMUDEEF TVQuran Channel

Read Quran

سُورَةُ التَّكۡوِيرِ

Suratul At-Takwir · 29 ayahs

  1. بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ إِذَا ٱلشَّمْسُ كُوِّرَتْ ﴿١﴾

    81:1Nígbà tí wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù,

  2. وَإِذَا ٱلنُّجُومُ ٱنكَدَرَتْ ﴿٢﴾

    81:2àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,

  3. وَإِذَا ٱلْجِبَالُ سُيِّرَتْ ﴿٣﴾

    81:3àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù),

  4. وَإِذَا ٱلْعِشَارُ عُطِّلَتْ ﴿٤﴾

    81:4àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì,

  5. وَإِذَا ٱلْوُحُوشُ حُشِرَتْ ﴿٥﴾

    81:5àti nígbà tí wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ,

  6. وَإِذَا ٱلْبِحَارُ سُجِّرَتْ ﴿٦﴾

    81:6àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná,

  7. وَإِذَا ٱلنُّفُوسُ زُوِّجَتْ ﴿٧﴾

    81:7àti nígbà tí wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)

  8. وَإِذَا ٱلْمَوْءُۥدَةُ سُئِلَتْ ﴿٨﴾

    81:8àti nígbà tí ọmọbìnrin tí wọ́n bò mọ́lẹ̀ láàyè bá bèèrè pé

  9. بِأَىِّ ذَنۢبٍۢ قُتِلَتْ ﴿٩﴾

    81:9ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n pa òun fún,

  10. وَإِذَا ٱلصُّحُفُ نُشِرَتْ ﴿١٠﴾

    81:10àti nígbà tí wọ́n bá ṣí àwọn tákàdá (iṣẹ́ ẹ̀dá) sílẹ̀,

  11. وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ كُشِطَتْ ﴿١١﴾

    81:11àti nígbà tí wọ́n bá ká sánmọ̀ kúrò lókè,

  12. وَإِذَا ٱلْجَحِيمُ سُعِّرَتْ ﴿١٢﴾

    81:12àti nígbà tí wọ́n bá mú iná Jẹhīm jò fòfò,

  13. وَإِذَا ٱلْجَنَّةُ أُزْلِفَتْ ﴿١٣﴾

    81:13àti nígbà tí wọ́n bá sún Ọgbà Ìdẹ̀ra mọ́ (àwọn onígbàgbọ́ òdodo),

  14. عَلِمَتْ نَفْسٌۭ مَّآ أَحْضَرَتْ ﴿١٤﴾

    81:14(nígbà náà ni) ẹ̀mí (kọ̀ọ̀kan) yóò mọ ohun tí ó mú wá (nínú iṣẹ́ ire àti iṣẹ́ ibi).

  15. فَلَآ أُقْسِمُ بِٱلْخُنَّسِ ﴿١٥﴾

    81:15Nítorí náà, Èmi (Allāhu) ń fi àwọn ìràwọ̀ tó ń yọ ní alẹ́, tó ń wọ̀ọ̀kùn ní ọ̀sán búra,

  16. ٱلْجَوَارِ ٱلْكُنَّسِ ﴿١٦﴾

    81:16(ìyẹn) àwọn ìràwọ̀ tó ń rìn lọ rìn bọ̀, tó ń wọ̀ọ̀kùn sí ibùwọ̀ wọn.

  17. وَٱلَّيْلِ إِذَا عَسْعَسَ ﴿١٧﴾

    81:17Mo tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá lọ búra.

  18. وَٱلصُّبْحِ إِذَا تَنَفَّسَ ﴿١٨﴾

    81:18Mo tún fi òwúrọ̀ nígbà tí ó bá mọ́lẹ̀ búra.

  19. إِنَّهُۥ لَقَوْلُ رَسُولٍۢ كَرِيمٍۢ ﴿١٩﴾

    81:19Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán Jibrīl) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé,

  20. ذِى قُوَّةٍ عِندَ ذِى ٱلْعَرْشِ مَكِينٍۢ ﴿٢٠﴾

    81:20alágbára, ẹni pàtàkì ní ọ̀dọ̀ Ẹni t’Ó ni Ìtẹ́-ọlá,

  21. مُّطَاعٍۢ ثَمَّ أَمِينٍۢ ﴿٢١﴾

    81:21ẹni tí wọ́n ń tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ níbẹ̀ yẹn (nínú sánmọ̀), olùfọkàntán.

  22. وَمَا صَاحِبُكُم بِمَجْنُونٍۢ ﴿٢٢﴾

    81:22Àti pé ẹni yín (Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) kì í ṣe wèrè.

  23. وَلَقَدْ رَءَاهُ بِٱلْأُفُقِ ٱلْمُبِينِ ﴿٢٣﴾

    81:23Ó kúkú rí i nínú òfurufú kedere.

  24. وَمَا هُوَ عَلَى ٱلْغَيْبِ بِضَنِينٍۢ ﴿٢٤﴾

    81:24Àti pé kì í ṣe ahun (tàbí ẹni-afurasí) lórí ìró ìkọ̀kọ̀ (tí A fi ránṣẹ́ sí i).

  25. وَمَا هُوَ بِقَوْلِ شَيْطَٰنٍۢ رَّجِيمٍۢ ﴿٢٥﴾

    81:25Al-Ƙur’ān kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Èṣù, ẹni ẹ̀kọ̀.

  26. فَأَيْنَ تَذْهَبُونَ ﴿٢٦﴾

    81:26Nítorí náà, ibo l’ẹ̀ ń lọ?

  27. إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرٌۭ لِّلْعَٰلَمِينَ ﴿٢٧﴾

    81:27Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.

  28. لِمَن شَآءَ مِنكُمْ أَن يَسْتَقِيمَ ﴿٢٨﴾

    81:28(Ó wà) fún ẹni tí ó bá fẹ́ nínú yín láti dúró déédé.

  29. وَمَا تَشَآءُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلْعَٰلَمِينَ ﴿٢٩﴾

    81:29Ẹ̀yin kò sì níí fẹ́ (láti dúró déédé) àyàfi tí Allāhu bá fẹ́, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni