Read Quran
سُورَةُ البَلَدِ
Suratul Al-Balad · 20 ayahs
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ لَآ أُقْسِمُ بِهَٰذَا ٱلْبَلَدِ ﴿١﴾
90:1Èmi (Allāhu) ń fi ìlú yìíbúra.
وَأَنتَ حِلٌّۢ بِهَٰذَا ٱلْبَلَدِ ﴿٢﴾
90:2Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).
وَوَالِدٍۢ وَمَا وَلَدَ ﴿٣﴾
90:3Èmi (Allāhu) ń fi òbí àti ohun tó bí búra.
لَقَدْ خَلَقْنَا ٱلْإِنسَٰنَ فِى كَبَدٍ ﴿٤﴾
90:4Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro.
أَيَحْسَبُ أَن لَّن يَقْدِرَ عَلَيْهِ أَحَدٌۭ ﴿٥﴾
90:5Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni?
يَقُولُ أَهْلَكْتُ مَالًۭا لُّبَدًا ﴿٦﴾
90:6Ó (sì) ń wí pé: “Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -)”
أَيَحْسَبُ أَن لَّمْ يَرَهُۥٓ أَحَدٌ ﴿٧﴾
90:7Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni?
أَلَمْ نَجْعَل لَّهُۥ عَيْنَيْنِ ﴿٨﴾
90:8Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un?
وَلِسَانًۭا وَشَفَتَيْنِ ﴿٩﴾
90:9Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)?
وَهَدَيْنَٰهُ ٱلنَّجْدَيْنِ ﴿١٠﴾
90:10A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n.
فَلَا ٱقْتَحَمَ ٱلْعَقَبَةَ ﴿١١﴾
90:11Kò sì lọ rin ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí níbi Iná!
وَمَآ أَدْرَىٰكَ مَا ٱلْعَقَبَةُ ﴿١٢﴾
90:12Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí?
فَكُّ رَقَبَةٍ ﴿١٣﴾
90:13(Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú.
أَوْ إِطْعَٰمٌۭ فِى يَوْمٍۢ ذِى مَسْغَبَةٍۢ ﴿١٤﴾
90:14Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi.
يَتِيمًۭا ذَا مَقْرَبَةٍ ﴿١٥﴾
90:15(Ẹ lè fún) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí,
أَوْ مِسْكِينًۭا ذَا مَتْرَبَةٍۢ ﴿١٦﴾
90:16tàbí mẹ̀kúnnù tí kò ní gá tí kò ní go (olòṣì paraku).
ثُمَّ كَانَ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوا۟ وَتَوَاصَوْا۟ بِٱلصَّبْرِ وَتَوَاصَوْا۟ بِٱلْمَرْحَمَةِ ﴿١٧﴾
90:17Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe.
أُو۟لَٰٓئِكَ أَصْحَٰبُ ٱلْمَيْمَنَةِ ﴿١٨﴾
90:18Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún.
وَٱلَّذِينَ كَفَرُوا۟ بِـَٔايَٰتِنَا هُمْ أَصْحَٰبُ ٱلْمَشْـَٔمَةِ ﴿١٩﴾
90:19Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì.
عَلَيْهِمْ نَارٌۭ مُّؤْصَدَةٌۢ ﴿٢٠﴾
90:20Wọ́n máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.
Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni