ALMUDEEF TVQuran Channel

Read Quran

سُورَةُ التَّكَاثُرِ

Suratul At-Takaathur · 8 ayahs

  1. بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ أَلْهَىٰكُمُ ٱلتَّكَاثُرُ ﴿١﴾

    102:1Wíwá oore ayé ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ fún ìyanràn ṣíṣe ti kó àìrójú fẹ́sìn ba yín

  2. حَتَّىٰ زُرْتُمُ ٱلْمَقَابِرَ ﴿٢﴾

    102:2títí ẹ fi wọ inú sàréè.

  3. كَلَّا سَوْفَ تَعْلَمُونَ ﴿٣﴾

    102:3Rárá (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́) láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.

  4. ثُمَّ كَلَّا سَوْفَ تَعْلَمُونَ ﴿٤﴾

    102:4Lẹ́yìn náà, ní ti òdodo, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.

  5. كَلَّا لَوْ تَعْلَمُونَ عِلْمَ ٱلْيَقِينِ ﴿٥﴾

    102:5Ní ti òdodo, tí ó bá jẹ́ pé ẹ ni ìmọ̀ àmọ̀dájú ni (ẹ̀yin ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀).

  6. لَتَرَوُنَّ ٱلْجَحِيمَ ﴿٦﴾

    102:6Dájúdájú ẹ máa rí iná Jẹhīm.

  7. ثُمَّ لَتَرَوُنَّهَا عَيْنَ ٱلْيَقِينِ ﴿٧﴾

    102:7Lẹ́yìn náà, dájúdájú ẹ máa fi ojú rí i ní àrídájú.

  8. ثُمَّ لَتُسْـَٔلُنَّ يَوْمَئِذٍ عَنِ ٱلنَّعِيمِ ﴿٨﴾

    102:8Lẹ́yìn náà, dájúdájú ní ọjọ́ yẹn wọ́n máa bi yín léèrè nípa ìgbádùn (ayé yìí).

Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni